Man U ti n fi ọna ẹyin han Ronaldo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, November 17, 2022

Man U ti n fi ọna ẹyin han Ronaldo


Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ bayii, o ti n daju gbangba wi pe ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ko nilo gbajugbaja agbabọọlu agbaye nni, Cristiano Ronaldo mọ.

Ojoojumọ ni wọn fi n kọrin owe fun Ronaldo, ẹni to ti gba aami ẹyẹ Ballon d’Or lẹẹmarun-un ọtọọtọ wi pe asiko rẹ ninu ikọ ẹgbẹ agbabọọlu naa ti n pe.

Laipẹ yii ni gbegede tun gbina nigba ti awọn alaṣẹ naa yọ aworan Ronaldo nla kan to wa lẹnu ọna abawọle si papa iṣere Old Trafford danu.

Bo tilẹ jẹ pe Manchester United sọ pe awọn yọ aworan naa kuro nitori idije agbaye ti Rugby, iyẹn Rugby League World Cup ni wọn ṣe yọ aworan naa kuro, ṣugbọn sibẹ, ohun to daju ni pe ikọ ẹgbẹ agbabọọlu naa ko fẹẹ Ronaldo mọ.

Ṣaaju asiko yii la gbọ pe Ronaldo ti ko awọn ọmọ rẹ kuro nileewe Man U, to si ko wọn lọ sileewe Portugal lorileede rẹ, nigba to mọ pe opin ti de ba oun ninu ẹgbẹ agbabọọlu Man U.

Atigba ti wọn ni Ronaldo ti ṣe ifọrọwerọ pẹlu Piers Morgan, nibi to ti tu pẹrẹpẹrẹ ọrọ nipa ohun ti wọn ṣe fun un ninu ẹgbẹ agbabọọlu ọhun, paapaa akọnimọọgba wọn, Erik Ten Hag ni nnkan ko ti fararọ mọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI