Wolii ijọ Kerubu to ja ibale ẹgbọn ati aburo l'Ogun dero atimọle - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 16, 2022

Wolii ijọ Kerubu to ja ibale ẹgbọn ati aburo l'Ogun dero atimọle


Ọmọ ọdun mẹrindinlogun ati ọmọ ọdun mẹtala, ti wọn jẹ ẹgbọn ati aburo ni Wolii ijọ Kerubu ati Serafu to wa ni Ajuwọn, ipinlẹ Ogun, Joseph Ogundeji ja ibale wọn lẹẹkan naa.

Joseph, ẹni ọgbọn ọdun naa ni iroyin fi to wa leti pe o fipa ja ibale awọn ọmọ naa, ti wọn jẹ ọmọ ijọ rẹ.

Pakopako ni Joseph n wo nigba ti ọwọ ọlọpaa tẹ ẹ lọjọ kọkanla, oṣu ti a wa yii, to si n bẹbẹ pe ki wọn fi oju aanu wo oun, nitori pe iṣẹ eṣu ni.

AWIKONKO gbọ pe baba awọn ọmọ naa lo lọ fi ẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa wi pe Joseph f'ipa ja ibale awọn ọmọ oun, leyi to fi lanfaani lati maa ba wọn laṣepọ karakara.

Wọn ni baba naa lo ṣakiyesi pe ọkan lara awọn ọmọ naa to jẹ agba, iyẹn ọmọ ọdun mẹrindinlogun ti loyun, to si beere ẹni to fun un leyun, eyi to pada jẹwọ pe Joseph, Wolii ijọ t'awọn n lọ ni.

Loju ẹsẹ ni wọn ti lọ gbe Joseph ni ṣọọṣi ẹ, to si pada jẹwọ pe lotitọ loun ba awọn ọmọ naa laṣepọ, lakoko iṣo-oru.
 
Awọn mejeeji nigba ti wọn n sọrọ, ṣalaye pe igbakugba t'awọn ba ti pari iṣọ-oru ni Joseph maa n sọ pe ki wọn lọ jokoo de nile rẹ ti ko jinna si ṣọọṣi, nigba ti wọn ba si debẹ, ṣe ni yoo gbe nnkan fun wọn lati gbe jẹ.
 
Bi wọn ba ti jẹ nnkan naa, wọn ko ni mọ ohun ti wọn n ṣe mọ, igba naa ni Joseph yoo raaye lati ba wọn laṣepọ. Ṣadede ni ọkan lara wọn loyun.
 
CP Lanre Bankọle to jẹ ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti wa paṣẹ pe ki iwadii tubọ tẹsiwaju lori Joseph, ko to di pe wọn foju ẹ ba ile ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI