O pari! Wọn sinku baale ile pẹlu tikẹẹti tẹtẹ 'Bet9ja' to ran-an lọ sọrun aremabọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 11, 2022

O pari! Wọn sinku baale ile pẹlu tikẹẹti tẹtẹ 'Bet9ja' to ran-an lọ sọrun aremabọ


Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii la ko tii le sọ pato ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, sibẹ, ohun t'awọn kan n sọ ni pe ohun oju wa loju ri fun ọkunrin kan to ku nitori bo ṣe padanu obitibiti owo to n reti nibi tẹtẹ to ta.
 
Tẹtẹ igbalode kan ti wọn pe ni 'Bet9ja' la gbọ pe ọkunrin naa ta, to si n reti lati jẹ miliọnu mẹrinlelọgbọn (N34m) naira, ati miliọnu meje le ni igba (N7.2m) naira.
 
AWIKONKO gbọ pe idije kọọkan lo ba tikẹẹti mejeeji naa jẹ, eyi ti ko jẹ ki owo to n reti wọle sii lapo, to si ṣe bẹẹ dagbere faye.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni aisan ẹjẹ riru n da ọkunrin naa laamu tẹlẹ, sugbọn nigba to ti gbọkan le owo naa pupọ, lo jẹ ki aisan naa gbọna miran yọ si i, to si ṣe bẹẹ mu idi lọ silẹ, ko to jade laye.
 
Ohun to wa jẹ iyalẹnu ni bi wọn ṣe l'awọn mọlẹbi rẹ le tikẹẹti mejeeji to ran an lọ sọrun mọ ara posi ti wọn fi sinku rẹ.

Inu oṣu kọkanla, ọdun 2019 ni iṣẹlẹ ọhum waye, ti awọn eeyan ṣi n ranti rẹ titi di asiko yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI