Ẹ wo oju Adetutu, arẹwa ọmọbinrin to bẹ sodo Third Main Land l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, November 11, 2022

Ẹ wo oju Adetutu, arẹwa ọmọbinrin to bẹ sodo Third Main Land l'Ekoo


Titi di asiko ti a pari iroyin yii, iyalẹnu ati kayeefi nla lọrọ arẹwa ọmọbinrin ti ẹ n wo yii, ẹni to binu bẹ sodo afara kẹta to wa nipinlẹ Eko ṣi n jẹ fun pupọ awọn to gbọ nipa rẹ, paapaa awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn.
 
Adetutu Adedokun ni wọn pe orukọ ọmọbinrin naa, ẹni ti wọn lo n ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ orileede yii, iyẹn Department of State Security Services, DSS, ẹka t'ipinlẹ Eko.
 
Nnkan bi aago mẹwaa, aarọ Ọjọbọ, Tọside to kọja yii ni wọn sọ pe Adetutu binu kuro ninu mọto to wọ, to si lọ fibinu bẹ sinu odo.
 
A gbọ pe mọto ero igbalode ti a mọ si Uber ni wọn sọ pe Adetutu wọ laaarọ ọjọ naa, inu mọto ọhun ni wọn sọ pe oun pẹlu ololufẹ rẹ to ṣẹṣẹ fun un loruka ifẹ loju awọn eeyan wọn ti jọ n fi ọrọ pẹẹta, wọn ni lojiji lo sọ pe ki awako naa duro.

Wọn ni awakọ naa ko mọ nnkan to n ṣẹlẹ, paapaa ipinu rẹ to fi duro, lojiji ni wọn lo lọ binu bẹ sodo lati gbẹmi ara rẹ.

Ileeṣẹ to n ri sọrọ iṣẹlẹ pajawiri n'ipinlẹ Eko, Lagos Emergency Management Agency (LASEMA) f'idi iṣẹlẹ ọhun mulẹ lati ẹnu akọwe agba ileeṣẹ naa, Olufẹmi Oke-Ọsanyintolu.
 
Awakọ naa nigba to n sọrọ, ṣalaye pe Adetutu ati ololufẹ rẹ ni wọn jọ n fa ọrọ laaarin ara wọn lori foonu, ko to di pe o sọ pe koun duro lojiji. O ni iyalẹnu lo jẹ foun pe niṣẹ lo lọ binu bẹ sodo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI