Ọdun mẹtalelọgbọn lori itẹ: Ẹ gbọ ohun ti AbdulRazaq sọ nipa Ẹmir ilu Ilọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, November 11, 2022

Ọdun mẹtalelọgbọn lori itẹ: Ẹ gbọ ohun ti AbdulRazaq sọ nipa Ẹmir ilu Ilọrin


Lonii ni Ọmọwe pe ọdun mẹtalelọgbọn lori itẹ awọn baba nla rẹ, ti Sheikh Alimi gẹgẹ bii Ẹmir ilu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, ti gbogbo awọn eeyan kaakiri agbaye si n kii ku oriire ayẹyẹ ayajọ naa.

Ninu awọn to n fi ọrọ ikini ranṣẹ si Ẹmir naa ni gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq, ẹni to ni ibaṣepọ to dan mọnran pẹlu Ẹmir.

AbdulRazaq, nigba to n ki ku ayajọ ọdun mẹtalelọgbọn naa, o ṣapejuwe Ẹmir gẹgẹ bi iranṣẹ Olodumare to duro fun apẹẹrẹ rere nipa idagbasoke, ifẹ ati iṣọkan araalu.

“Mo lewaju awọn araalu ati ijọba ipinlẹ Kwara lati ki Alayeluwa, Mai Martaba, Ẹmir ilu Ilọrin fun aṣeyọri nla yii. Ijọba rẹ kii ṣe nipa alaafia nikan, o tun ti mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba Ilọrin. Labẹ rẹ ni awọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin ati araalu fi gun oke agba, ti wọn si n ṣe aṣeyọri lẹka gbogbo ti wọn ti n ba ara wọn, to fi mọ eto oṣelu ati ọrọ aje.

“Gẹgẹ alakoso eto iṣejọba, a n dupẹ gidigidi lọwọ Alayeluwa fun ifọwọsowọpọ, amọran baba, ati adari eto ọba, gbogbo eyi to ti ṣe iranwọ nla, to si n ro ipinlẹ wa lagbara nipa idagbasoke to lọọrin. Nipa awọn igbarukuti yii ni a fi n gbiyanju lati tun olu-ilu wa ṣe, lati dun-un wo loju fun gbogbo aye.”

AbdulRazaq wa gbadura alaafia ati ẹmi gigun fun Mai Martaba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI