Ọrẹ mẹta to n ji mọto gbe laaarin Abẹokuta ti ha o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 13, 2022

Ọrẹ mẹta to n ji mọto gbe laaarin Abẹokuta ti ha o


Boroboro bayii ni awọn ọrẹ mẹta ti wọn sọ pe wọn ko n'iṣẹ meji ju ki wọn maa ji mọto onimọto gbe nibi ti wọn ba gbe e si n ka lọgba ọlọpaa titi di asiko yii.
 
Mọto onimọto meji ọtọọtọ la gbọ pe wọn ka mọ wọn lọwọ l'ọsẹ to kọja yii, eyi ti wọn ti n wa tipẹtipẹ.
 
Moses Adewale Abiọdun, Ṣeyi Oyenẹkan ati Mọnsuru Majẹkodunmi lorukọ awọn mẹtẹẹta ti wọn sọ pe iṣẹ ole mọto jijigbe ni wọn yan laayo, ti wọn si ti ji ọpọ ,ọto gbe, ko to di pe ọwọ palaba wọn segi.
 
Kii ṣe pe akara wọn deede tu s'epo lọjọ kẹsan, oṣu ti a wa yii, bi ko ṣe pẹ ẹnikan ti wọn pe orukọ rẹ ni Oluṣesi Akingbile to n gbe ladugbo Ijẹmọ lo lọ teṣan ọlọpaa Oke-Itoku niluu Abẹokuta lati lọ ṣalaye wi pe oun kori mọto oun , toun gbe siwaju ita ile tun n gbe.
 
Ọjọ kejila, oṣu kẹwaa, ọdun yii ni ọkunrin naa sọ pe wọn ji mọto oun gbe, ati pe gbogbo igbesẹ lati ri mọto oun naa, Toyota Carina E ti nọmba idanimọ rẹ jẹ AAB 567 TF lo ja si pabo, eyi lo jẹ k'awọn ọlọpaa bẹrẹ iṣẹ iwadii wọn.
 
Wọn ni loju ẹsẹ lawọn ọlọpaa ti ta gbogbo ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ati agbegbe rẹ lolobo nipa mọto naa, eyi to jẹ ki gbogbo wọn wa ni ifura si iru awọn mọto naa.
 
AWIKONKO gbọ pe ṣadede l'awọn ọlọpaa Kemta, Idi-Aba kofiri mọto naa ni ọgba mẹkaniiki to wa loju ọna Ajebọ, iyẹn lọjọ kẹsan, oṣu yii.
 
Wọn ko fi ọrọ naa falẹ rara ti wọn fi da mọto naa duro, to si jẹ pe Moses Adewale Abiọdun ni wọn ba ninu ẹ, ẹni ti ko le ṣalaye ibi to ti mọto ọhun.
 
Bayii ni wọn bẹrẹ sii fọrọ wa a lẹnu wo, to si jẹ ko di mimọ nibẹ pe awọn meji kan ṣi wa ti wọn jọ n ṣiṣẹ, ti awọn ọlọpaa si lọ ko wọn.
 
O tun jẹ ohun iyalẹnu nigba ti wọn tun ri iru mọto naa to jẹ alawọ buluu, eyi nọmba idanimọ rẹ AAA 565 GJ gba lọwọ wọn, mọto naa ni wọn sọ pe wọn jigbe.
 
Ṣugbọn ni bayii, ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki iwadii tubọ tẹsiwaju, ki wọn si rii pe wọn ṣe iwadii finnifinni ko to di pe wọn foju wọn ba ile-ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI