Bi ọmọ Yewa ko ba gbaruku ti Biyi Ọtẹgbẹyẹ lọdun 2023, wọn ko le gboorun ipo gomina mọ l’ọdun 2027 – Muyiwa Ọladipọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 15, 2022

Bi ọmọ Yewa ko ba gbaruku ti Biyi Ọtẹgbẹyẹ lọdun 2023, wọn ko le gboorun ipo gomina mọ l’ọdun 2027 – Muyiwa Ọladipọ


Kọmiṣanna fọrọ eto aṣa ati irin-ajo afẹ lasiko iṣejọba ana nipinlẹ Ogun, Baṣhọrun Muyiwa Ọladipọ ti sọ pe anfaani kan ṣoṣo ti gbogbo ọmọ ilẹ Yewa jakejado agbaye ni ree lati gba ipo gomina, to si ni bi wọn ko ba gbaruku ti oludije kan ṣoṣo to wa nita lasiko yii, ko daju pe wọn yoo tun gboorun ipo naa mọ titi ayeraye.


Baṣhọrun Ọladipọ, ẹni to ti f’igba kan ri jẹ olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun lasiko iṣakoso Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba, to tun jẹ kọmiṣanna fọrọ eto oye jijẹ ati ijọba ibilẹ ni saa akọkọfun Sẹnetọ Ibikunle Amosun lo sọrọ naa lọsẹ to kọja yii lakoko to n b’AWIKONKO sọrọ ni ọfiisi rẹ to wa niluu Abẹokuta.

Ọmọ bibi ilu Ijẹbu naa ni latigba ti wọn ti da ipinlẹ Ogun silẹ, awọn Yewa laarin eya meta ti won pin ipinle naa si ko tii de ipo gomina ri, to si ni anfaani nla ree lati lati de ipo naa.

Ninu oro re, o ni 
“Ni ti Biyi Ọtẹgbẹyẹ, lati ọdun 1976 ti wọn ti da ipinlẹ Ogun silẹ, ọmọ Yewa kan ko tii di gomina, ṣe ni wọn n fi ori awọn Yewa gba ara wọn kaakiri, lati le jẹ ki wọn padanu, eyi ti ko jẹ ki gbogbo wọn le fi ẹnu ko lori oludije kan ṣoṣo. L’ọdun 1992, nigba ti oludije meji jade laaarin gbungbun ipinlẹ Ogun, ẹ maa ranti pe ko sẹni to jade lati Ogun East nitori Bisi Ọnabanjọ. Titi Ajanaku ati Ṣẹgun Ọṣọba ni wọn jọ jade du ipo gomina, ko to di pe Ajanaku juwọ silẹ fun Ọṣọba. Awọn bii mẹfa ni wọn jade ni Yewa lati du ipo gomina, gbogbo wọn ni ko gba funra wọn lati juwọ silẹ f’ẹnikan.

L’ọdun 1999, awọn meji lo tun jade lati Ogun Central, Ọṣọba ati Fẹmi Okunrounmu. Nigba ti Ọṣọba ko gbogbo ibo ni Ogun East ati Ogun Central, ṣe ni awọn oludije lati Yewa pin ibo mọ ara wọn lọwọ. Bẹẹ naa lo ri lọdun 2011, GNI ati Olurin ni wọn jọ jade ni Yewa. GNI ati Sẹnetọ Ọdunsi ni wọn jọ jade. GNI ati Triple A ni wọn jọ forigbari lati Yewa. Fun igba akọkọ ninu itan ilẹ Yewa, wọn n fa oludije kan ṣoṣo kalẹ fun ipo gomina, leyi to jẹ Amofin Biyi Ọtẹgbẹyẹ, to si wa a jẹ pe Ọtẹgbẹyẹ ati ijọba APC to wa nibẹ bayii.

Fun idi eyi, mi o ri nnkan to buru nibẹ lati ri ọmoọ Yewa, ko di gomina lọdun 2023 to n bọ yii. O jẹ ohun to gbọdọ wa si imuṣẹ lati rii pe ọmọ Yewa di gomina lọdun 2023, ju wi pe wọn n duro de ọdun 2027 lọ, nitori pe ko sẹni to le sọ ohun ti yoo ṣẹlẹ, bo tilẹ jẹ pe lasiko yii, gẹgẹ bi ofin ajọ eleto idibo, ko s’anfaani mọ lati sọ pe eeyan kan tun n jade lati du ipo gomina bayii.

A le ni oludije to ju mẹta, mẹrin lọ lati Yewa lọdun 2027, ṣugbọn asiko naa ree lati tete beere fun ẹtọ wọn. To ba di 2027, ti oludije kan ba jade lati aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, o ti di dandan wi pe awa ti a wa lati Ogun East ko nii gbe apoti ibo, eyi yoo si fun awọn aarin gbungbun lanfaani lati jawe olubori. Awọn Yewa yoo si tun pin ibo laaarin awọn oludije wọn, ki ni a wa n sọ, ẹ jẹ ka sọ otitọ to wa nilẹ.”

Bẹẹ lo tun fi kun ọrọ rẹ pe lotitọ, Dapọ Abiọdun lo yẹ koun tẹle gẹgẹ bi ọmọ ilu oun, ṣugbọn to ni oun ko tun le ṣatilẹyin fun un mọ, nitori to ti ja gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun kulẹ, toun si ri ọjọ iwaju rere fun ipinlẹ naa ninu Biyi Ọtẹgbẹyẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI