Oriire nla: Irinṣẹ eto ayewo ilera igbalode olowo nla wọ ipinlẹ Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 30, 2022

Oriire nla: Irinṣẹ eto ayewo ilera igbalode olowo nla wọ ipinlẹ Kwara


Inu idunnu ati ayọ nla l'awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara wa titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii pẹlu bi ijọba apapọ orileede Naijiria ṣe fi irinṣẹ ayewo eto ilera igbalode ta wọn lọrẹ.

Ajọ kan ti wọn pe ni Nigerian Sovereign Investment Authority Healthcare Development and Investment Company (NHDIC) la gbọ pe o tọwọ bọ iwe adehun pẹlu ijọba ipinlẹ Kwara lori eto kan ti wọn pe ni Diagnostics and Oncology Expansion Programme lati mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba eto ilera.
 
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe eyi yoo ṣe iranwọ fun eto ilera araalu nipa kikọ ibudo ti wọn yoo maa mojuto s'iluu Ilọrin, eyi ti yoo jẹ aladani alabóde f'awọn araalu.

Wọn ni ipinlẹ Kwara wa lara awọn ipinlẹ to wa ni ipele akọkọ bii Kaduna ati Enugu, eyi ti wọn sọ pe ajọ Nigerian Sovereign Investment Authority (NSIA) ati ipinlẹ ti wọn ba kọ ibudo naa si ni yoo maa fọwọsowọpọ lati mojuto wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI