Oyetọla sọ iye to fi silẹ gẹgẹ bii gomina to kogba wọle, l'awọn eeyan ba ni opurọ ni - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 28, 2022

Oyetọla sọ iye to fi silẹ gẹgẹ bii gomina to kogba wọle, l'awọn eeyan ba ni opurọ ni


Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe Alaaji Gboyega Oyetọla ti gbe ijọba kalẹ gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ọṣun, ti Sẹnetọ Ademọla Adeleke si ti gbakoso bayii.
 
Ṣugbọn sibẹ, awọn eeyan ṣi n sọrọ lori iye owo ti gomina ana, Oyetọla loun fi silẹ ninu apo owo ipinlẹ Ọṣun, to si ni k'awọn eeyan mọ bi nnkan ṣe n lọ, ko to di pe ijọba to wa nibẹ yii yoo bẹrẹ sii sọ iṣokuso.
 
Oyetọla ninu ọrọ to sọ lakoko to n gbe ijọba silẹ, o ni biliọnu mẹrinla naira loun fi silẹ ninu apo owo ipinlẹ naa fun ijọba tuntun ti wọn bura fun, iyẹn Adeleke.
 
Siwaju sii ni Oyetọla sọ pe gbese biliọnu mẹtadinlọgọrun-un naira toun ba nilẹ lakoko toun gbajọba lọdun 2018, toun si loun ko figba kan ya owo lati mu eto ọrọ aje ipinlẹ naa dagba, bi ko ṣe pe owo to n wọle l'awọn n na fun idagbasoke.
 
Ṣugbọn pupọ ninu awọn to gbọ si ọrọ ti Oyetọla sọ yii ni wọn ni ko si otitọ kankan ninu ọrọ rẹ, bi ko ṣe pe ọrọ oṣelu lasan ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI