Qatar fi agbako bẹrẹ idije ife ẹyẹ agbaye 2022, wọn tun f'itan buruku balẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 20, 2022

Qatar fi agbako bẹrẹ idije ife ẹyẹ agbaye 2022, wọn tun f'itan buruku balẹ


Iya nla lo gbe orileede Qatar ṣanlẹ lonii, ọjọ Aiku, Sannde ti idije ife ẹyẹ agbaye bẹrẹ lorileede ọhun, pẹlu bi wọn ṣe gba aami ayo meji lọwọ orileede Ecuador, ti wọn ko si ri anfaani lati da ẹyọkan pada.
 
Orileede Qatar lo gbalejo awọn orileede agbaye ninu idije ife ẹyẹ agbaye to bẹrẹ lonii lorileede wọn. Awọn si ni wọn fi iya ainitiju bẹrẹ idije ọhun nigba ti orileede Ecuador lu wọn lalubami pẹlu omi iṣanwọ.
 
Aami ayo meji si oodo ni idije naa to waye ni papa iṣere Al Bayt pari si.
 
Bo tilẹ jẹ pe orileede Qatar ni ọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu, paapaa awọn ero iworan ṣatilẹyin fun, ṣugbọn to pada jẹ pe itiju nla lo pada gbẹyin wọn.
 
Ipele akọkọ ifigagbaga naa, iyẹn 'first half' ni orileede Ecuador ti gba aami ayo meji naa wọle Qatar, ṣugbọn nigba ti yoo fi di ipele keji, awọn agbabọọlu Qatar naa gbiyanju pupọ, ṣugbọn ti ẹpa ko pada boro fun wọn.
 
Ninu ifẹsẹwọnsẹ to waye lonii ni Qatar ti fi itan tuntun balẹ, eyi ti ko ṣẹlẹ ri ninu idije ife ẹyẹ agbaye. Awọn ni orileede akọkọ to n gbalejo awọn orileede, ti wọn yoo fi iya bẹrẹ idije.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI