Wọn ju baale ile satimọle nitori ẹsun didana sun ṣọọṣi l'Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 15, 2022

Wọn ju baale ile satimọle nitori ẹsun didana sun ṣọọṣi l'Ondo


Ile-ẹjọ majisireeti to wa n'ijọba ibilẹ Odigbo, ipinlẹ Ondo ti paṣẹ pe ki wọn lọ ju baala ile, ẹni ọdun marundinlaadọta kan, Joseph Adeoye satimọle lori ẹsun didana sun ṣọọṣi ati ile onile.
 
Ṣọọṣi ati ile naa ni wọn sọ pe owo rẹ ko din ni miliọnu mẹwaa naira, eyi ti wọn ni Adeoye at'awọn meje kan, t'awọn ti juba ehoro lọ dana sun ninu oṣu kẹsan, ọdun yii.
 
Abule ti wọn pe Alagbado to wa lagbegbe ọrẹ ni wọn sọ pe ṣọọṣi ati ile naa wa.
 
Gẹgẹ bi agbefọba, Usifo James ṣe ṣalaye niwaju ile ẹjọ, o ni ẹsun ti wọn fi kan Adeoye tako iwe ọdaran ti abala 516 ati 443 t'ipinlẹ Ondo, t'ọdun 2006.
 
Ṣugbọn nigba toun naa n sọrọ, Adeoye loun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun plẹlu alaye, bo tilẹ jẹ pe ko tii ri alaye naa ṣe, ko to di pe ile-ẹjọ paṣẹ lati lọ ju sahamọ.
 
Onidajọ agba D. O Ogunfuyi to paṣẹ pe ọgba ẹwọn Okitipupa ni ki wọn lọ ti Adeoye mọ, titi digba ti igbẹjọ yoo waye lọjọ kẹsan, oṣu kejila, ọdun yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI