2023: Aderinokun nikan lo kun oju oṣuwon lati ṣoju aarin gbungbun ipinlẹ Ogun - Awọn ọlọja - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, December 22, 2022

2023: Aderinokun nikan lo kun oju oṣuwon lati ṣoju aarin gbungbun ipinlẹ Ogun - Awọn ọlọja


Gbogbo awọn ọlọja kaakiri aarin gbungbun ipinlẹ Ogun ti sọ ọ sita gbangba wi pe ẹnikan ṣoṣo t'awọn nigbagbọ ninu ẹ lati ṣoju awọn nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja, ni Oloye Olumide Aderinokun to n dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP.

Awọn olori ọlọja lo fidi ọrọ naa mulẹ l'Ọjọru, Wẹsidee to kọja, koda ti wọn tun gbadura fun ẹni ti ọkan wọn n fẹ lati jawe olubori.

Nigba to n lewaju awọn ọlọja nibi ipade ti wọn ti ṣeleri atilẹyin wọn ninu gbọnga Ake, Iyalọja ilu Ẹgba, Oloye Oluwakẹmi Abẹkẹ Oloyede ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa awọn ohun to n jẹ wọn niya.

O si rọ oludije naa lati wa ọna abayọ si awọn iṣoro ọhun ni kete to ba de ori ipo aṣofin to n lọ.

Aderinokun ninu ọrọ rẹ si wọn, gba gbogbo wọn lamọran lati tete lọ gba kaadi idibo alalopẹ wọn, ki wọn le lanfaani lati dibo.

O ni lotitọ loun mọ pe ìjọba to wa nita lakoko yii n fi ẹtọ wọn dun wọn, ṣugbọn to ṣeleri wi pe oun yoo ṣe gbogbo ojiṣe to ba tọ lati ṣe ni kete to ba ti wọle.

Lara awọn olori ọlọja to tun wa nibẹ ni Ọtun Iyalọja, Oloye Janeth Gbadebọ; Baba Iyalọja Ẹgba, Oloye Tayọ Bamidele; Babalọja Kutọ, Oloye Abraham Ọlabinke, at'awọn miran.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI