2023: Mo ti ṣetan lati jẹ k'awọn araalu jẹ mudunmudun eto iṣejọba awa-ara-wa - Ọnarebu Micky Kazzim - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 21, 2022

2023: Mo ti ṣetan lati jẹ k'awọn araalu jẹ mudunmudun eto iṣejọba awa-ara-wa - Ọnarebu Micky Kazzim


Gbajugbaja oloṣelu nni, Ọnarebu Mikail Kazzim ti ọpọ awọn eeyan mọ si Micky Kazzim ti jẹ ko di mimọ fun gbogbo awọn ara agbegbe Guusu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun wi pe oun yoo mu eto igbayegbadun wa fawọn toun fẹẹ lọ ṣoju niluu Abuja.

Ọnarebu Micky Kazzim to n dije du ipo aṣoju-ṣofin nile igbimọ aṣofin kekere l'Abuja labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Allied People's Movement, APM lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade to fi ranṣẹ si AWIKONKO laipẹ yii.


Bi a ba n sọ nipa awọn oloṣelu to gbajumọ daadaa nipinlẹ Ogun, odu ni Ọnarebu Micky Kazzim, kii ṣaimọ foloko, paapaa lẹkun aarin gbungbun ipinlẹ naa.

Ninu atẹjade naa ti ọkunrin to ti figba kan asoju sofin labe egbe oselu APC, lagbegbe yii tele tun fikun oro e pe oun yoo tubo sagbega idagbasoke, imayederun ati ipese ise fawon odo ti won yoo fi ni ipin ninu mudunmudun ijoba ara wa. 

Micky tun fikun ninu oro e pe bi oun se darapo mo egbe oselu APM, ki i nipa imotara eni bi ko se lati sise po pelu  awon ti imo ati oye won jo dogba, ti won le mu anfaani bawon eeyan agbegbe Abeokuta South. 

O so pe," Mi o fe ki enikeni si mi gbo o, ti mo ba so pe APC ati APM, je omo baba kan naa, sugbon ti iya won yato. Bi a ba ni ka wo bi won se da egbe mejeeji sile, ko si nnkan teeyan fi le so pe iyato wa. 


"Bi igba ti omo ba pada wale ni ipadabo mi lati APC si APM, eyi to si se pataki ni ki gbogbo awon oludibo atawon omo egbe oselu APM, ni agbegbe Abeokuta South, je ka jo sise po, ki a le se aseyori nla".

Oludije APM, tun salaye pe ifowosowopo 
awon araalu yii lo je ki erongba won jo lori idagbasoke ati imayederun awujo, ti yoo si fopin si iponju, ti awon odo naa yoo si je anfaani idagbasoke laaarin won. 

Bee lo tun so idi to fi wa dije ni Abeokuta South dipo Abeokuta North, o ni anfaani nla ni yoo je lati tun le se awon ise akanse toun ti se nigba toun fi soju won nigba naa. 


Micky Kazzim, waa so pe ko tan sibe o, nitori oun ti lawon igbese kan sile toun yoo  gunle, bi won ba le fi ibo won gbe oun wole. 

O wa menuba lara awon akanse to ti se ti akosile e si wa titi di oni, eyi to fi mu ayipada rere bawon eeyan agbegbe Abeokuta South. 

Lara e lawon ise akanse to se si gbogbo Abeokuta South, ileewe alakobere mefa, ti won tun ko, to si ti di ohun elo titi di akoko yii. 

Awon ileewe naa ni  Our Lady of the Lords, ,Onikoko, Abeokuta. Methodist Primary School, Imo, Oke-yeke, Abeokuta, St Augustine Primary School, Adatan, Abeokuta.  Atawon mii-in.


Bakan naa ni Micky Kazzim, tun ti sise akanse lori, ilera, eto eko, ona ati beebee lo, tawon akanse ise yii si wa di oni. 
  
Micky Kazzim, tun salaye idi to fi jade ni agbegbe Abeokuta South ,fun ipo asoju -sofin, o so pe ojulowo omo Abeokuta loun lati Abeokuta South ati Abeokuta North. 

O ni ijoba ibile Abeokuta ni mejeeji n je tele, ko to di pe won pin won lati le je ki idagbasoke tubo bawon. 

O so pe, "Gege bi ojulowo omo Abeokuta, ti mo le soju ibi to ba wu mi lawon ekun mefa to se pataki nibe.

Awon naa ni Ake, Gbagura, Owu, Osile, ati Ibara.  Eyi see se nitori ko si beeyan se le nile baba ko ma ni ti iya. Mo n soju agboole Lumosa ni woodu kefa, Oke-Id, ni Gbagura, ni Abeokuta North ".

Ni bayii, oun dije lati soju agboole Lumoye ni woodu kin in ni, Eruwon, Abeokuta South . O ni fawon to ba fee mo Eruwon ni abule iya iya mi ti emi atawon ebi mi maa n lo lakooko odun nigba ta a wa ni kekere. 

O waa lo akoko yii lati ro awon eeyan agbegbe Abeokuta South, lati fowosowopo fi ibo gbe oun wole lodun 2023. Pelu ileri pe oun ko nii jawon nitanmo. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI