2023: Dapọ Abiọdun fẹẹ fi ile ẹgbẹ ipolongo idibo aarẹ lelẹ l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, December 8, 2022

2023: Dapọ Abiọdun fẹẹ fi ile ẹgbẹ ipolongo idibo aarẹ lelẹ l'Abẹokuta


Gbogbo eto lo ti pari fun gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun lati ṣiṣọ logun eegun ile ẹgbẹ fun ipolongo idibo aarẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC n'ipinlẹ naa.
 
Ninu atẹjade ti Tunde Ọladunjoye, ẹni to jẹ akọwe ipolongo ẹgbẹ APC n'ipinlẹ Ogun fi sita nirọlẹ oni, Ọjọbọ, Tọsidee lo ti sọ pe alakoso eto ipolongo idibo nipinlẹ Ogun, Dapọ Abiọdun ti pari gbogbo eto.

Ọladunjoye ni ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹwaa, oṣu kejila, ọdun 2023 ni eto ọhun yoo waye niwaju ọfiisi gomina to wa ni Oke-Mọsan, Abẹokuta.
 
Bakan naa lo tun sọ pe Dapọ Abiọdun yoo tun lo anfaani naa lati fi oju awọn igbimọ ipolongo naa han f'awọn eeyan lọjọ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI