Ijọba Kwara fẹẹ f'awọn araalu l'awọọdu opin ọdun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, December 8, 2022

Ijọba Kwara fẹẹ f'awọn araalu l'awọọdu opin ọdun


Gẹgẹ bi ọrọ Yoruba to sọ pe 'inu didun lo n mu koriya wa', bẹẹ lọrọ ri n'ipinlẹ Kwara pẹlu ijọba ṣe ti n palẹmọ akanṣe eto lati mọ riri awọn araalu to ti ko ipa jọju ninu idagbasoke ipinlẹ naa.
 
AWIKONKO gbọ pe gbogbo eto lo ti pari bayii fun ijọba Kwara lati fun gbogbo awọn to peregede julọ ni aami ẹyẹ opin ọdun, eyi to fẹ fi mọ riri ipa ti ẹnikọọkan n ko ninu eto ilọsiwaju ipinlẹ naa.
 
Ọpọ awọn ọmọ bibi ipinlẹ naa la gbọ pe ijọba ti pari eto lati fun wọn ni aami ẹyẹ nipa bi wọn ṣe n gbe orukọ Kwara ga ni gbogbo ẹka iṣẹ ti wọn ti n ṣe daadaa lorileede Naijiria ati lagbaye.

Ọjọ Ẹti, Furaide, ọjọ kẹtalelogun, oṣu kejila, ọdun 2023 ni eto naa yoo waye ni gbọngan Banquet to wa niluu Ilọrin, ipinlẹ naa.
 
Eyi lo si fi n han daju pe Gomina AbdulRahman AbdulRazaq karamsiki awọn eeyan rẹ, to fẹran iṣẹ ilọsiwaju nipa mi mọ riri b'awọn ọmọ ipinlẹ ọhun ṣe n gbe orukọ ilu wọn ga.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI