2023: Ẹ ṣọra f'awọn oloṣelu ẹlẹnu didun lasiko yii - Aderinokun gbawọn araalu lamọran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 7, 2022

2023: Ẹ ṣọra f'awọn oloṣelu ẹlẹnu didun lasiko yii - Aderinokun gbawọn araalu lamọran


Oludije sipo ile igbimọ aṣofin agba lorileede yii labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP nipinlẹ Ogun, Oloye Olumide Aderinokun ti gba awọn araalu lamọran lati ṣọra f'awọn oloṣelu ẹlẹnu didun bi eto idibo ṣe n wọle de.
 
Aderinokun sọ pe ẹlẹtan lo pọ ninu awọn oludije lawọn ẹgbẹ oṣelu to yatọ sẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ naa, paapaa lorileede Naijiria. O ni ẹtanjẹ ni wọn n ba kaakiri, lati le ri ipo oṣelu ti wọn n du gba.
 
Ọkunrin naa lo sọrọ yii nibi ayẹyẹ ọlọdọọdun t'awọn aranṣọ, iyẹn Association of Tailors and Fashion Designers, ẹka tipinlẹ Ogun ṣe laipẹ yii niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.
 
Gbajugbaja oloṣelu naa to n jade lati ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ naa sọ pe ọna lati de ipo agbara ni wọn n wa kaakiri, eyi ti wọn yoo fi maa ṣe ileri ohun ti wọn ko le ṣe bi wọn ba de ipo ti wọn n wa.
 
O ni gbogbo ọna lawọn oloṣelu n wa lati rii pe wọn de ipo ti wọn yoo fi ko araalu si gbese ayeraye, ti wọn yoo si da ọjọ ọla awọn ogowẹẹrẹ to n bọ ru, eyi to n gba wọn lamọran lati wo iru ẹni ti wọn yoo dibo fun.
 
 
 
"Ọdun mẹtala sẹyin ni mo darapọ mọ oṣelu, ṣugbọn ko si nnkan meji to mu mi jade lati du ipo bi ko ṣe ipenija to n koju araalu lorileede yii. Oniṣowo to n ṣe daadaa lẹnu iṣẹ rẹ ni mi, ti mo si ni oniruuru ohun ti mo ti fi owo de mọlẹ, ṣugbọn sibẹ, iyẹn ko sọ pe koun kawọ gbera, ki Naijria wa darikodo patapata.

"Gbogbo wa la mo ohun to n ṣẹlẹ kaakiri orileede yii, paapaa julọ nipinlẹ Ogun ti a wa yii. Aisi eto aabo, agbe okoowo ti ko wu ni lori, aisi iṣẹ, ọna ti ko dara, ati bẹẹbẹẹlọ, eyi ti gbogbo yin naa mọ nipa ẹ.

"Mo fẹẹ bẹ yin tọkantọkan wi pe ẹ ma ṣe jẹ ki wọn koo yin laya jẹ lati dibo fun ikuna, ẹ dibo f'awọn to ni ifẹ araalu lọkan. Ẹ ma jẹ ka tun pada ṣe aṣiṣe mọ, nitori pẹ a ti fara da iya ọdun mẹrin.

"Mo ti ṣetan lati ṣoju gbogbo yin nile igbimọ aṣofin agba lorileede yii, maa si rii daju pe awọn ẹtọ to ba yẹ ni mo ṣe fawọn eeyan mi lẹkun mẹfẹẹfa to sọ aarin gbungbun ipinlẹ Ogun."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI