Awọn olokoowo kekeeke tun jẹ anfaani ọtun lọwọ ijọba Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 7, 2022

Awọn olokoowo kekeeke tun jẹ anfaani ọtun lọwọ ijọba Kwara


Oriire nla gbaa lo jẹ fun gbogbo awọn olokoowo kekeeke kaakiri ipinlẹ Kwara pẹlu bi ijṣe gbe iranlọwọ dide fun wọn nipa eto ẹyawo ti ko ga ni lara.
 
Awọn olokoowo kekeeke ti wọn pe ni Small and Medium Enterprises (SMEs) la gbọ pe ijọba Kwara gbe eto ẹyawo kalẹ fun, pẹlu erongba lati jẹ ki ọrọ aje wọn ati ipinlẹ naa ni ilọsiwaju to ye kooro.

Ohun ti a gbọ pe olokoowo ti ko din ni 450 lo jẹ anfaani eto ẹyawo naa ti ko ni ele lori.
 
Wọn ni b'awọn kan ṣe gba miliọnu kan aabọ naira, naa lawọn miran gba miliọnu meji nairan lati fi mu idagbasoke ba okoowo wọn.

Lara awọno okoowo yii ni wọn n ṣe iṣẹ iwe titẹ, aṣọ riran, ile didanu, iṣẹ agbẹ ati bẹẹbẹẹlọ.
 
Hussein Ahmed (N1.5m); Azeez Akeem (N1.5m); Soliu Muhammed Lanre (N2m); Oladunni Kafilat Olaide (N2m); Femi Peter (N1.5m); Sanusi Ismail Adeshina (N2m); Ali Michael (N2m); Kareem Naimat (N2m); Adebayo Hadiat Tinuola (N1.5); ati Abdulrauf Abdulraheem (N1.5m).

A gbọ pe awọn akọpa ti ko din ni 15,708 lo fi orukọ silẹ, to si jẹ pe lẹyin idanwo ati ayẹwo loriṣiriṣi, wọn peregede.
 
Diẹ ree lara bi fọto eto naa ṣe lọ:No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI