2023: Naijiria maa dorikodo patapata bi Tinubu ba fi tipatipa fa ara rẹ le awọn araalu lori - Wolii Ayọdele ju bọmbu asọtẹlẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, December 25, 2022

2023: Naijiria maa dorikodo patapata bi Tinubu ba fi tipatipa fa ara rẹ le awọn araalu lori - Wolii Ayọdele ju bọmbu asọtẹlẹ


Gbajugbaja Wolii agbaye nii, Wolii Elijah Babatunde Ayọdele, alaṣẹ ati olusile ijọ INRI Evangelical Spiritual Church ti sọ pe orileede Naijiria yoo dorikodo patapata bi oludije sipo Aarẹ lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ba fi tipatipa fa ara rẹ le awọn araalu lori lọdun 2023.

Fun awọn to ba mọ bi nnkan ṣe n lọ daadaa lasiko yii, paapaa ninu eto idibo to n bọ lọna lọdun 2023, Tinubu nikan lo gbajumo daadaa laaarin awọn oludije, ti ọpọ si n'igbagbọ pe yoo wọle gẹgẹ bi aarẹ.

Wolii Ayọdele lọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii lo sọ ọ di mimọ pe ko si ohun rere kan ti yoo ṣẹlẹ fun Naijiria labẹ iṣakoso Tinubu gẹgẹ bi aarẹ.

Ilu mọ-ọn-ka alasọtẹlẹ naa lo sọ ọrọ yii nibi akanṣe àsọtẹlẹ ọlọdọọdun to maa n waye ni ṣọọṣi ẹ to wa niluu Eko, nibi to ti tu pẹrẹpẹẹrẹ asọtẹlẹ awọn ohun ti yoo ṣẹlẹ lọdun 2023 lorileede Naijiria ati ni gbogbo agbaye.

Bo tilẹ jẹ pe Wolii Ayọdele ko sọ ẹni ti yoo jawe olubori ninu eto idibo Aarẹ lọdun to n bọ, sibẹ o sọ pe ẹnikan ṣoṣo toun rii pe yoo tukọ Naijiria daadaa ni Peter Obi, oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour.

O ni idibo ọdun 2023 ko le fi ibi kankan dabi eyi to waye lọdun 1993, eyi ti Oloogbe Mọṣhood Abiọla ti jawe olubori, bo tilẹ jẹ pe wọn ko kede re.

Wolii Ayọdele ni ko si oludije kankan ti yoo ko ibo rẹpẹtẹ bii ti igba Abiọla ninu eto idibo to n bọ yii, ati pe ko si aṣeyọri rere kan ti yoo pada jade lẹyin eto idibo ọhun.

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe orileede Naijiria nilo adura pupọ lakoko yii nitori pe awọn ipinlẹ kọọkan ko nii ṣe daadaa, ati pe awọn olori wọn ko nii mo ọna abayọ, nitori pe gbogbo nnkan yoo daru mọ wọn loju.

Nigba to n kadi ọrọ rẹ, o ni ayafi bi awọn ọmọ Naijiria ba jawọ kuro ninu gbigba owo lọwọ awọn oloṣelu ki wọn too dibo, tabi ki wọn dibo nitori ẹgunjẹ, orileede yii ko nii lọ siwaju, bẹẹ si ni iṣẹ ati oṣi yoo tubọ maa pọ sii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI