Ẹgbẹ akọroyin ipinlẹ Ogun tu gbogbo igbimọ to wa nilẹ tẹlẹ ka - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, December 25, 2022

Ẹgbẹ akọroyin ipinlẹ Ogun tu gbogbo igbimọ to wa nilẹ tẹlẹ ka


Alaga ẹgbẹ awọn akọroyin lorileede Naijiria, ẹka ti ipinlẹ Ogun ti tu gbogbo igbimọ ti wọn yan tẹlẹ lati maa tukọ iṣakoso ka patapata lai fi akoko ṣofo.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, alaga tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ Ogun, Kọmireedi Wale Ọlanrewaju lo paṣẹ naa ninu atẹjade to fi sita lati ọwọ akọwe ẹgbẹ naa, Kọmureedi Bunmi Adigun lọjọ Abamẹta, Satide to kọja.

O ni gbogbo igbimọ ti wọn yan lati tukọ eto idibo to waye kọja lọ, loun ti tuka, nitori pe wọn ko wulo mọ fun wọn.

Bakan naa lo tun fi kun ọrọ rẹ wi pe igbimọ ti wọn yan lati tukọ eto ariyanjiyan laaarin awọn to jade du ipo, iyẹn Political Debate Committee ko gbẹyin ninu igbimọ ti wọn tuka.
 
Siwaju sii lo paṣẹ pe ki awọn igbimọ naa da gbogbo dukia ẹgbẹ akọroyin to wa ni ikawọ wọn si silẹ pada laaarin asiko naa titi di Ọjọru, Wẹsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2022 ti a wa yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI