Abba Kyari lo ni ka purọ mọ Saraki, ko mọ nnkankan nipa banki t'awọn adigunjale kọlu l'Ọffa - Ẹlẹrii jẹwọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, December 9, 2022

Abba Kyari lo ni ka purọ mọ Saraki, ko mọ nnkankan nipa banki t'awọn adigunjale kọlu l'Ọffa - Ẹlẹrii jẹwọ


Ọkan lara awọn ẹlẹrii to n jẹri niwaju ile ẹjọ giga t'ipinlẹ Kwara, Shamsudeen Bada, l'Ọjọbọ, Tọsidee to kọja yii ti sọ pe gomina tẹlẹri n'ipinlẹ naa, Sẹnetọ Bukọla Saraki ko mọ nnkankan nipa banki ti wọn lọ kogun ja l'ọjọ karun-un, oṣu kẹrin, ọdun
2018 niluu Ọffa.

Bada sọ pe igbakeji ọga ọlọpaa ti ẹka ọtẹlẹmuyẹ, Abba Kyari lo ni k'awọn purọ mọ Saraki, ẹni to tun jẹ Aarẹ ile igbimọ aṣofin ana lorileede Naijiria, pẹlu erongba lati ko ba a.

O ni ṣe ni Abba Kyari lu oun gidigidi lati tako Saraki niwaju ile-ẹjọ.

Awọn marun-un, Ayọade Akinnibọsun, Ibikunle Ogunlẹyẹ, Adeọla Abraham, at'awọn meji miran ni ileeṣẹ ọlọpaa f'oju wọn ba ile ẹjọ, pẹlu ẹsun ti wọn fi kan wọn pe wọn mọ nipa banki Ọffa t'awọn adigunjale kọlu.
 
Bada sọ pe nigba ti awọn mọlẹbi awọn ti ko ko sahamọ fi ile-ẹjọ dunkooko mọ awọn ọlọpaa, ẹka ileeṣẹ ọlọpaa, iyẹn IRT sọ pe aṣẹ tawọn n gba wa lati ọdọ ọga wọn, ko si si ile ẹjọ kankan n'ipinlẹ Kwara to le da wọn duro.
 
O ni Abba Kyari ṣeleri wi pe awọn yoo gba ominira bi wọn ba ti le purọ mọ Saraki wi pe oun lo ran wọn niṣẹ lati lọ digun ja banki naa lole, to si ni ibọn ni wọn fi fọ Ayọ Akinnibọsun lẹsẹ nigba to sọ pe oun ko le purọ mọ Saraki.
 
“Lẹyin ti wọn yinbọon fun Ayọ, aisan kọlu mi. Abba Kyari lo mu nọọsi wa lati tọju mi. Ko to di pe wọn fi mi silẹ, awọn ọlọpaa ni mo gbọdọ ṣeleri f'awọn wi pe mi o gbọdọ b'awọn akọroyin sọrọ, mi o si gbọdọ yọju sile ẹjọ lati jẹrii, ati pe mo gbọdọ fi oṣelu silẹ.”
 
Nigba ti awọn agbefọba ko le ko awọn iwe ẹri kan silẹ, wọn bẹbẹ lati sun igbẹjọ siwaju.
 
Onidajọ Halimat Salman wa paṣẹ pe igbẹjọ yoo waye lọjọ kẹrindinlogun, ọjọ kẹtadinlogun ati ọjọ kejidinlogun, oṣu kinni, ọdun 2023.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI