Ọgba ẹwọn ni Tunji to fipa ja ibale ọmọ ọdun mẹsan l'Ondo yoo ti ṣ'ọdun Keresimesi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, December 9, 2022

Ọgba ẹwọn ni Tunji to fipa ja ibale ọmọ ọdun mẹsan l'Ondo yoo ti ṣ'ọdun Keresimesi


Ile-ẹjọ giga ti ipinlẹ Ondo ti paṣẹ pe ki gendekunrin kan, Tunji Aboriṣade to f'ipa ja ibale ọmọ ọdun mẹsan n'ipinlẹ naa ṣi lọ gbadun ara rẹ l'ọgba ẹwọn titi di  ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2023 ti igbẹjọ yoo tun pada waye.
 
AWIKONKO gbọ pe nnkan bi aago mẹwaa aarọ, ọjọ kọkanlelogun, oṣu keji, ọdun 2022 ti a wa yii ni Tunji f'ipa ba ọmọ naa laṣepọ ninu ọgba ile-ẹkọ girama t'awọn ọlọpaa, iyẹn Police Secondary Barracks to wa lagbegbe Iju-Itaogbolu, ijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, ipinlẹ Ondo.
 
B.B. Ọlarewaju to jẹ agbefọba nigba to n fẹsun kan Tunji niwaju ile-ẹjọ sọ pe niṣẹ lọkunrin naa kọkọ ba ọmọ naa ṣere ibalopọ ti ko bojumu, ko to ja ibale rẹ.
 
Ẹsun yii lo sọ pe o tako iwe ofin to nii ṣe pẹlu ẹtọ awọn ọmọde (Ondo State Child’s Right Law, 2007), abala 31(1), 31(2).
 
A gbọ pe ẹsun ti wọn fi kan Tunji ko lanfaani lati bẹbẹ.
 
Agbefọba naa wa rọ ile ẹjọ lati sun igbẹjọ siwaju, lati le tubọ ṣiṣẹ iwadii kikun, eyi ti yoo jẹ ki wọn mu awọn ẹlẹri wa siwaju ile-ẹjọ naa.
 
Bakan naa, agbẹjọro fun Tunji, Tolulọpẹ Adebiyi, parọwa si ile-ẹjọ lati f'oju aanu wo onibara oun, nitori pe o ti ṣetan lati koju igbẹjọ ti yoo ba waye.
 
Nigba to n sọrọ, Onidajọ Yẹmi Fasanmi paṣẹ pe ki wọn ṣi lọ fi Tunji pamọ sọgba ẹwọn Olokuta, to si sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kinni, ati ọjọ kẹfa, o'su keji, ọdun 2023.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI