Awọn agbẹ ati opo tun bọ saye nla ni Kwara, miliọnu mẹtalelaadọta nijọba fẹẹ fun wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, December 8, 2022

Awọn agbẹ ati opo tun bọ saye nla ni Kwara, miliọnu mẹtalelaadọta nijọba fẹẹ fun wọn


Lasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, inu idunnu ati ayọ nla l'awọn olugbe ipinlẹ Kwara, paapaa awọn agbẹ ati opo wa pẹlu bi ijọba ipinlẹ naa ṣe gbe eto ẹyawo onirọrun kalẹ fun wọn.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni miliọnu mẹtalelaadọta le diẹ ijọba ipinlẹ naa fẹẹ gbe kalẹ fun wọn lati maa fi tẹsiwaju ninu okoowo wọn.
 
Ileeṣẹ ijọba apapọ orileede yii to n ri sọrọ ajalu ati idagbasoke, iyẹn Federal Ministry of Humanitarian, Disaster Management and Social Development la gbọ pe wọn jọ tọwọ bọwe adehun pẹlu ijọba ipinlẹ Kwara lati ṣe iranwọ f'awọn eeyan nipinlẹ naa.
 
Ẹgbẹrun lọna ogun naira niroyin fi to wa leti pe awọn eeyan to le ni ẹgbẹrun meji aabọ, 2,655 yoo gba labẹ akanṣe eto ti wọn pe ni FG's Grant Vulnerable Groups programme (GVG), eyi to wa f'awọn to ku diẹ kaato fun, nipele akọkọ.

AWIKONKO gbọ pe awọn mejeeji yii tun gbe ipele keji dide labẹ eto ti wọn pe ni Government Enterprise Empowerment Programme (GEEP 2.0), eyi ti Aarẹ Muhammadu Buhari gbe kalẹ lati fi ṣe iranwọ f'awọn agbẹ to le ni ẹgbẹrun mẹfa, 6,086, to fi mọ awọj olokoowo, opo ati awọn ti wọn ko si nile ọkọ, eyi ti wọn pe ni National Social Investment Programme (N-SIP). 

Eto naa la gbọ pe o waye lẹyin wakati mẹrinlelogun ti ijọba gbe iranwọ dide f'awọn ọdọ to din die ni ẹẹdẹgbẹta, 490 labẹ eto Kwaprenuour (3.0). Eto ẹyawo ti ko ni ele lori, nibi ti awọn ọdọ ti gbaiwe sọwedowo miliọnu kan aabọ si miliọnu meji naira.

Nibi ti wọn ti ṣiṣọ loju eto naa l'Ọjọru, Wẹsidee ni minisita, Hajia Sadiya Umar Farouq ti rọ gbogbo awọn to jẹ anfaani naa lati ṣamulo owo ti wọn gba gẹgẹ bo ti tọ, ki wọn le daa pada bo ti yẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI