Ọwọ tẹ Buhari atawọn eeyan rẹ meji to ji tanka epo salọ ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, December 8, 2022

Ọwọ tẹ Buhari atawọn eeyan rẹ meji to ji tanka epo salọ ni Kwara


Ọwọ awọn ẹṣọ aabo ara ẹni laabo ilu ti a mọ si Sifu Difẹnsi, ẹka tipinlẹ Kwara ti tẹ gendekunrin mẹta kan ti wọn sọ pe wọn niṣẹ meji ju ki wọn maa ji epo bẹntiroolu orileede yii gbe salọ.
 
Ọga agba fun Difẹnsi nipinlẹ Kwara, Ibrahim Tukur lo tu aṣiri naa niluu Ilọrin lonii, Ọjọbọ, Tọsidee, to si ni wọn yoo foju winna ofin lẹyin ti iwadii ba tubọ pari.
 
A gbọ pe ẹnikan ti wọn pe ni Buhari Joda, ẹni ọdun mẹtadinlogoji lo wa tanka epo to jẹ lita ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn naa salọ, ti wọn si ni ileepo kan ti wọn pe ni Ọladeji, eyi to wa niluu Ilọrin lo lọ ta a si.

Ibi to ti n ja epo naa la gbọ pe ọwọ ti tẹ ẹ l'Ọjọru, Wẹsidee ana lọwọ ti tẹ ẹ.
 
Tukur ni lita ẹgbẹrun mejilelogun ni Buhari kọkọ ja fun ileepo Ọladeji to wa niluu Ilọrin, to si lọ ja lita ẹgbẹrun mọkan yooku si ileepo Ọladeji naa to wa lagbegbe Oko-Olowo, iyẹn niluu Ilọrin.
 
Ileepo mejeeji yii ni iroyin fi to wa leti wi pe wọn ti ti pa ni kete ti aṣiri tu, ti a si gbọ pe iwadii ti n lọ lọwọ lẹkunrẹrẹ.
 
Ileepo kan to wa niluu Ikorodu, ipinlẹ Eko lo yẹ ki Buhari gbe tanka epo naa lọ, ko to jẹ pe ilu Ilọrin lo gbe e salọ.

Tukur darukọ awọn meji yooku gẹgẹ bii Hamidu Joda, ẹni ọdun mejilelọgbọn ati Buhari Aminu toun jẹ ọmọ ogun ọdun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI