Ẹ tete lọ gba kaadi idibo yin o - Dapọ Abiọdun gb'awọn musulumi lamọran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, December 25, 2022

Ẹ tete lọ gba kaadi idibo yin o - Dapọ Abiọdun gb'awọn musulumi lamọran


Bi eto idibo ọdun 2023 ṣe n sunmọ etile, Gomina Dapọ Abiọdun ti gba gbogbo ọmọ ẹlẹsin musulumi kaakiri orileede Naijiria, paapaa ipinlẹ Ogun lamọran lati tete lọ gba kaadi idibo alalopẹ wọn ki asiko too lọ.

Gomina Abiọdun lo fi ọrọ amọran yii sita nibi ayẹyẹ ipagọ ọlọdọọdun ti ijọ Ahmadiyya Muslim Jama'at, ikejidinlaadọrin iru ẹ to waye ni papa Jamia Ahmadiyya to wa niluu Ilaro, ipinlẹ naa laipẹ yii.
 
Nibẹ ni gomina ti sọ pe ojuṣe gbogbo araalu, paapaa musulumi ni lati dibo yan adari ti wọn ba n fẹ ko dari wọn. O ni kii ṣe ojuṣe ara wọn ni eto idibo jẹ nikan, bi ko ṣe pe Allah ni wọn tun n ṣe e fun.

O ni latigba ti iṣakoso ti ori aga aleefa ni'ipinlẹ naa loun ti rii daju pe gbogbo agbara ti awọn adari n lo lọ silẹ patapata, ti ko si si idunkoko lẹka eto oṣelu si araalu.

Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe oun ti ṣe akitiyan to pọ lati rii pe irẹpọ wa laaarin awọn ẹlẹsin gbogbo, nipa gbigba ifẹ ati alaafia laaye laaarin ara wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI