Keresimesi: Gomina AbdulRazaq b'awọn Kristẹẹni yọ, o tun ṣapejuwe Keresi lara-ọtọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, December 25, 2022

Keresimesi: Gomina AbdulRazaq b'awọn Kristẹẹni yọ, o tun ṣapejuwe Keresi lara-ọtọ


Bi gbogbo awọn Kristẹẹni ṣe n ṣajọyọ ọjọ ibi Jesu Kristi kaakiri agbaye, ti wọn si n ki ara wọn ku oriire, naa ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ba gbogbo wọn yọ patapata.
 
Gomina AbdulRazaq ṣapejuwe ayẹyẹ ọlọdọọdun naa gẹgẹ bi eyi to ṣara-ọtọ lati yọ ninu ẹ, ati lati ṣe amulo aanu Ọlọrun ati ọjọ ibi Jesu Kristi.

Ninu lẹta ikini ti gomina fi ranṣẹ s'awọn ọmọlẹyin Jesu, o dupẹ lọwọ wọn fun ifẹ ti wọn ni si iṣakoso oun, ati bi wọn ṣe jẹ ọkan pataki lara awọn alafọwọsowọpọ ninu iṣakoso oun, eyi to n mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba ipinlẹ Kwara ni gbogbo igba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI