Ẹ wo aragbayamuyamu ile iwosan to pọ ju owo rẹ lọ, eyi tijọba Kwara fẹẹ ṣi l'opin ọsẹ yii - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, December 20, 2022

Ẹ wo aragbayamuyamu ile iwosan to pọ ju owo rẹ lọ, eyi tijọba Kwara fẹẹ ṣi l'opin ọsẹ yii


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii lawọn eeyan ṣi n beere pe ṣe lotitọ ni ijọba Kwara labẹ Gomina Abdulrahman Abdulrazaq fi ọọdunrun miliọnu ataabọ anira kọ aragbayamuyamu ile iwosan ti ẹ n wo yii.
 
Bawọn kan ṣe n sọ pe owo naa kere si iye ti wọn le fi kọ iru ile iwosan bayii, bẹẹ lawọn kan n sọ pe ile iwosan ọhun pọ ju owo rẹ lọ, ṣugbọn sibẹ, ohun ti ọpọ awọn araalu n sọ ni pe olotitọ eeyan ati adari to ṣee fọkan tan ni gomina wọn.
 
Ijọba ipinlẹ Kwara ti wa kede sita wi pe ile iwosan naa ti wọn fi ọọdun miliọnu ataabọ N350m naira kọ lawọn yoo ṣi lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kejila, ọdun 2022 ti a ṣi wa ninu ẹ yii, ti yoo si di lilo fun gbogbo araalu patapata.

Gbogbo awọn ohun elo ilera ti wọn fi n tọju awọn alaisan patapata lo jẹ pe wọn ba ti igbalode mu, ti ẹnikẹni ko si nilo lati lọ gba itọju mọ niluu Oyinbo.
 
Ilu Ọffa ni ijọba Kwara fori ile iwosan tuntun naa sọlẹ si, ninu ọgba ile iwosan ijọba, iyẹn Jẹnẹra Ọsibitu, Ọffa.

Oniruuru awọn irinṣẹ igbalode ti wọn fi n ṣayẹwo lo kun ibẹ, bi eyi ti wọn fi n ya ifun, egungun, apa ati bẹẹbẹẹlọ.
 
Yatọ si eyi, awọn ohun ẹrọ amunawa wọn lo duro digbi, ti ko si nii si iṣoro aisi ina mọnamọna.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI