O ma ṣe o! Wọn ni Sẹlimọt, oṣiṣẹ NTA ni reluwee pa danu l'Abuja - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, December 16, 2022

O ma ṣe o! Wọn ni Sẹlimọt, oṣiṣẹ NTA ni reluwee pa danu l'Abuja


Ileeṣẹ amohunmaworan ti orileede Naijiria, Nigeria Television Authority ti sọ pe ọkan lara awọn oṣiṣẹ wọn ni obinrin ti ọkọ oju irin, iyẹn reluwee pa danu l'Ọjọbọ, Tọsidee to kọja yii.
 
Obinrin naa ni wọn pe orukọ rẹ ni Sẹlimọt Idowu Suleiman, ẹni ti wọn sọ pe nnkan bi aago mẹwaa aarọ ni reluwee naa run ọkọ Toyota Camry rẹ womuwomu lagbegbe Chikakore to wa ni Kubwa, Abuja.
 
Ẹka ileeṣẹ NTA ti a mọ si ikanni karun-un, NTA Channel 5 ni Sẹlimọt n ba ṣiṣẹ, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
Ọga oluṣiro owo lẹka to n mojuto owo nina, Principal Accountant - Finance Department.

Ibi iṣẹ ni wọn lo n lọ laaarọ ọjọ buruku eṣu gbomimu naa, ko to pade agbako. Wọn ni ṣe ni Sẹlimọt fẹẹ tete kọja ki ọkọ oju irin naa too de ọdọ rẹ, lai mọ pe ere ni reluwee naa n ba bọ.
Ki oloju too ṣẹ ẹ, wọn ni reluwee naa ti kan an lara.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ilu Abuja, Josephine Adeh, f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ, to si ni adanu nla to kọminu ni iṣẹlẹ ọhun jẹ.
 
Ni bayii, a gbọ pe wọn sinku ọbinrin naa nilana musulumi.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI