Ilegbee f'awọn araalu jẹ ijọba logun gidi - AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, December 20, 2022

Ilegbee f'awọn araalu jẹ ijọba logun gidi - AbdulRazaq


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina Abdurahman Abdulrazaq ti jẹ ko di mimọ pe lara awọn ohun to jẹ ohun logun julọ ni ibi t'awọn eeyan yoo fori wọn pamọ si, bi wọn ba ṣe n pari iṣẹ oojọ wọn, eyi to mu ki wọn gbe igbesẹ lati kọ ogunlọgọ ile ti owo rẹ ko nii ga awọn araalu lara.
 
AbdulRazaq lo sọ eyi di mimọ nigba to n ṣiṣọ loju eegun ilegbee t'ijọba apapọ fi lelẹ labẹ eto kan ti wọn pe ni National Housing Programme (NHP), ipele akọkọ rẹ ti wọn n kọ soju ọna Asa Damn, Ilọrin.
 
O ni oriṣiriṣi ẹka ilegbee ni ijọba n gbiyanju lati ṣe agbekalẹ rẹ kaakiri ipinlẹ naa fun igbayegbadun awọn araalu.

Kọmiṣanna f'ọrọ eto ilegbee ati idagbasoke igberiko, Aliyu Muhammad Saifuddeem to ṣoju gomina gbe oṣuba kare fun Aarẹ Muhammadu Buhari ati mimisita f'ọrọ eto ilegbee ati akanṣe iṣẹ, Babatunde Raji Fashola fun bi wọn ṣe n gbe anfaani ti ko wọpọ wa si ipinlẹ Kwara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI