Alaṣe, oludasilẹ ati olori ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Wolii Elijah Ayọdele ti gba awọn oloṣelu Naijiria lamọran lati yee tunmọ awọn asọtẹlẹ rẹ si ara wọn, to si loun ko tii sọ ẹni tabi ẹgbẹ oṣelu ti yoo jawe olubori ninu eto idibo aarẹ to n bọ lọdun 2023.
Wolii Ayọdele sọ pe ọpọ awọn oloṣelu ni wọn ti n kaakiri wi pe oun ti sọ pe awọn ni yoo jawe olubori, eyi ti ko ri bẹẹ rara, o ni ṣe l'awọn oloṣelu naa n tan ara wọn jẹ lasan ni.
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin agba ojiṣẹ Ọlọrun naa,Ọgbẹni Ọṣhọ Oluwatosin gbe jade laipẹ, eyi to fi ranṣẹ s'AWIKONKO lo ti sọrọ naa, to si gba awọn eeyan lamọran lati ma ṣe gba iroyin ẹlẹjẹ t'awọn oloṣelu n gbe kaakiri nipa asọtẹlẹ Wolii Ayọdele gbọ.
O ni Wolii Ayọdele ko f'igba kan sọ asọtẹlẹ wi pe ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ni yoo jawe olubori ninu eto idibo Aarẹ lọdun 2023, bi ko ṣe pe o ṣe ikilọ nla fun gbogbo awọn to gbajumọ daadaa ninu eto idibo to n bọ lọna.
Siwaju sii lo sọ pe fọnran Wolii Ayọdele ti wọn yọ ayederu iroyin naa ninu ẹ, ojiṣẹ Ọlọrun naa ko sọ ẹni ti yoo jawe olubori ninu eto idibo 2023, bi ko ṣe pe o n ṣe ikilọ fun awọn oludije lẹgbẹẹ PDP ati Labour wi pe ki wọn ma ṣe jokoo tẹtẹrẹ, nitori pe gbogbo ọna ni APC n wa lati jawe olubori.
Ọṣhọ gba awọn akọroyin lamọran lati maa ni imọ kikun nipa oniruuru iroyin ti wọn ba n gbe jade, dipo ki wọn maa gbe ayederu iroyin kaakiri, eyi ti yoo pada ṣe akoba fun gbogbo awọn iroyin wọn.
Asọtẹlẹ Wolii Ayọdele sọ pe
"Ẹgbẹ oṣelu PDP ati Labour ko tii ṣetan fun eto idibo yii. Ohun ti mo n sọ yii ni mo ri mọjumọ. Oluwa sọ pe APC ti ṣetan lati gbe gbogbo eto kalẹ; yala lọna to ba ofin mu ni, tabi lọna awuruju lati rii pe wọn peregede ninu idibo yii.
"Bi ẹ ba si n fi oju yẹpẹrẹ wọn, wọn maa wa nibẹ, ohun to kan daju ni pe Tinubu ko nii ṣe saa keji, bi ẹ ba gba a laaye."
Ọshọ sọ pe ko si ibikibi ninu ọrọ yii ti Wolii Ayọdele ti sọ pe Tinubu ni yoo jawe olubori, to si ni ọkan pataki lara awọn ti ko gba tikẹẹti Musulumi ati Musulumi ni Wolii naa jẹ, to si sọrọ lati bu ẹnu atẹ lu ipo ti Tinubu n lọ fun laimọye igba.
O fi kun ọrọ rẹ pe ojiṣẹ Ọlọrun naa ko si lara awọn Wolii to n fi ẹnu meji sọrọ, to si ni bi Ọlọrun ba ṣe fi han an, lo ṣe n sọ ọ jade sita.
No comments:
Post a Comment