Omi tuntun ti ru: Ọlanrewaju di alaga tuntun fẹgbẹ akọroyin ipinlẹ Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, December 22, 2022

Omi tuntun ti ru: Ọlanrewaju di alaga tuntun fẹgbẹ akọroyin ipinlẹ Ogun


Ṣẹnkẹn bayii ni inu gbogbo awọn akọroyin kaakiri ipinlẹ Ogun n dun lori bi wọn ṣe dibo yan alaga tuntun ti yoo tukọ ẹgbẹ naa f'ọdun mẹta si asiko yii.
 
Victor Akinwale Ọlanrewaju, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Wale Centrism lo jawe olubori nibi eto idibo to waye lonii, Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu kejila, ọdun 2022.
 
Inu ọgba awọn akọroyin to wa ni Iwe-Irohin, Oke-Ilewo niluu Abẹokuta ni eto idibo ọhun ti waye, ti gbogbo awọn akọroyin si ti kii ku oriire, pẹlu ileri wi pe wọn yoo ṣatilẹyin fun un.
 
AWIKONKO gbọ pe ibo 165 ni Ọlanrewaju fi lewaju alatako rẹ, Olurẹmi Olugbenro toun ni ibo 149.
 
Ṣe ni idunnu ṣubu lu ayọ nla nigba ti awọn alakoso eto idibo naa kede Ọlanrewaju lati ẹka ẹgbẹ akọroyin ti State Information gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori lati di alaga tuntun.
 
Yatọ si Ọlanrewaju, lara awọn to tun jawe olubori ni Abiọdun Lawal lati ẹka aṣojukọroyin toun jẹ igbakeji alaga; Bunmi Adigun lati ẹka OGTV toun jẹ akọwe ẹgbẹ; Toyin Oyelumade lati ẹka OGBC, toun jẹ igbakeji akọwe; Idris Adelakun lati ẹka OGBC toun jẹ akapo ati Babatunde Ọdunewu toun jẹ ayẹwe owo wo.
 
Ipo kan yooku to ṣofo, iyẹn akọwe owo la gbọ pe awọn oloye tuntun naa yoo yan laaarin ara wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI