Keresimesi: Oluṣẹgun MacGregor, Ọba tuntun niluu Ilawọ pin ounjẹ fun ẹgbẹrun mẹwaa araalu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, December 24, 2022

Keresimesi: Oluṣẹgun MacGregor, Ọba tuntun niluu Ilawọ pin ounjẹ fun ẹgbẹrun mẹwaa araalu


Ṣe ni idunnu ṣubu lu ayọ awọn araalu Ilawọ ati agbegbe rẹ, nigba ti Ọba tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan laipẹ yii, Oluṣẹgun Alexander MacGregor pin ounjẹ ọdun Keresimesi f'awọn araalu.
 
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ṣe sọ, wọn ni araalu to le ni ẹgbẹrun mẹwaa ni Ọba MacGregor pin f'awọn araalu lati fi ṣayẹyẹ ọdun Keresimesi to wọle de yii.
 
Wọn ni b'awọn ọmọde ṣe gba ounjẹ, naa l'awọn arugbo, baale ati iyale ile naa gba ounjẹ wọn lọtọọtọ lai si ojusaaju ninu pinpin rẹ.
 
Lara awọn to wa nibẹ, ti wọn gbe iroyin naa si wa leti sọ pe ounjẹ ti ẹnikọọkan gba fun ọdun ko din ni ẹgbẹrun meje naira, lati fi ṣe ọdun to wa nita yii.


Ile iṣẹmbaye ti MacGregor, iyẹn MacGregor Heritage House to wa niluu Abẹokuta ni Ọba tuntun naa ti pin ounjẹ ọhun f'awọn araalu, to fi mọ awọn oloye ilu, lai yọ ẹnikẹni silẹ.

Nigba to n sọrọ, MacGregor, ẹni to tun jẹ Olunla ilu Ilawọ sọ pe bo tilẹ jẹ pe kii ṣe akọkọ ree toun yoo maa pin ounjẹ f'awọn araalu lati fi ṣọdun lai ṣe ojusaaju, sibẹ o ni ọna lati jẹ k'awọn to ku diẹ kaato fun naa kopa ninu pọpọṣinṣin ọdun lo fa a toun fi gbe eto ọhun kalẹ.

O ni awọn eeyan oun jẹ oun logun gidi, idi ree toun fi gbọdọ maa wa ọna abayọ si iṣoro wọn ni gbogbo igba, paapaa lasiko ọdun bayii.

O wa gba awọn eeyan lamọran lati ṣọdun niwọnba, ki wọn si lo anfaani ọdun naa lati sunmọ Ọlọrun nipa gbigba alaafia ati iṣọkan laaye laaarin ilu.

Diẹ ree lara awọn fọto bi eto ọhun ṣe lọ si:
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI