Aderinokun pin ounjẹ ọdun fawọn eeyan nijọba ibilẹ mẹfa to wa laaarin gbungbun ipinlẹ Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, December 24, 2022

Aderinokun pin ounjẹ ọdun fawọn eeyan nijọba ibilẹ mẹfa to wa laaarin gbungbun ipinlẹ Ogun


Inu idunnu ati ayọ nla ni gbogbo awọn araalu to wa nijọba ibilẹ mẹfa to wa ni aarin gbungbun ipinlẹ naa wa, nigba ti Oloye Olumide Aderinokun fi ounjẹ ọdun keresimesi ranṣẹ si wọn.

Aderinokun, oludije sipo aṣofin l'Abuja lati ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun lo fi ẹmi imoore han si awọn araalu, to si loun fẹẹ dẹrin pẹẹkẹ awọn eeyan.

Baagi irẹsi, adiẹ ọdun, ati awọn oniruuru oúnjẹ la gbọ pe Aderinokun fi ranṣẹ s'awọn eeyan naa.

Gbogbo awọn to wa nijọba ibilẹ Abẹokuta South, Abeokuta North, Ọbafẹmi Owode, Ọdẹda, Ifọ ati Ewekoro ni wọn jẹ anfaani yii.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI