O ma ṣe o: Sir Kay, gbajumọ oṣere tiata jade laye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 28, 2022

O ma ṣe o: Sir Kay, gbajumọ oṣere tiata jade laye


Iroyin ibanujẹ lo tun wọ agboole awọn oṣere tiata pẹlu bi wọn ṣe padanu ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ wọn, iyẹn Kamal Adebayọ, ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si Sir Kay.

Sir Kay lo fẹran lati maa ṣe tọọgi ninu fiimu lọpọ igba, pẹlu awọn aṣa loriṣiriṣi, eyi to maa n jẹ k'awọn eeyan gba tiẹ.

Bi Sir Kay ṣe jẹ oṣere tiata, naa lo tun jẹ ọkan pataki lara awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto nipinlẹ Eko, labẹ Alaaji Musiliu Akinsanya ti a mọ si MC Oluọmọ.

F'awọn ti ko ba mọ, Sir Kay ni baba to bi gbajugbaja oṣere oniṣẹju peretr, iyẹn Skit Maker, Abidemi Adebayọ, ẹni ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Isbae U.

Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni a ko tii le sọ iru iku to pa Sir Kay, ṣugbọn sibẹ ọkunrin naa jẹ ọlọwọ ọtun MC Oluọmọ.

Oluọmọ funra rẹ lo kede iku Sir Kay lori ikanni ayelujara ti abanidọrẹ, iyẹn Fesibuuku, to si gbadura pe ki Ọlọrun tẹ ẹ si afẹfẹ rere.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI