Tete maa gbaradi lati kọ iwe igbejọbasilẹ, nitori ko si ibi to n lọ lọdun 2023 yatọ si ile rẹ - PDP gba Dapọ Abiọdun lamọran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 28, 2022

Tete maa gbaradi lati kọ iwe igbejọbasilẹ, nitori ko si ibi to n lọ lọdun 2023 yatọ si ile rẹ - PDP gba Dapọ Abiọdun lamọran


Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP nipinlẹ Ogun ti gba Gomina Dapọ Abiọdun lamọran lati tete maa gbaradi lati kọ iwe igbejọbasilẹ, ti a mọ si 'Handing-Over Note', nitori ti wọn sọ pe ko si ibi kankan to n lọ ninu eto idibo ọdun 2023 to n bọ lọna.
 
Alaga ẹgbẹ naa, Ọnarebu Sikirulai Ọlawale Ogundele lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan to gbe sita, eyi to fi n tako ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ naa wi pe awọn tọọgi wọn n ba patako ipolongo ẹgbẹ PDP jẹ.

Alaga naa l'ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ana sọ pe gbogbo patako ipolongo awọn oludije lẹgbẹ oṣelu PDP, eyi to wa niluu Ipẹru, ijọba ibilẹ Ikẹnnẹ l'awọn tọọgi PDP ti bajẹ patapata.
 
Ninu atẹjade naa lo ti bu ẹnu atẹ lu bi ẹgbẹ oṣelu APC ṣe n ṣe oṣelu wọn lasiko yii, pẹlu bo ṣe sọ pe oṣelu ti wọn n ṣe ko yatọ si oṣelu ẹtaanu, eyi to ni ko bojumu.
 
Ogundele sọ pe onikaluku lo lẹtọọ labẹ ofin orileede Naijiria lati jade du ipo oṣelu, ti wọn si tun lẹtọọ lati ṣe ipolongo ni oniruuru ọna ti onikaluku ba mọ lati gbe ipolongo rẹ gba.
 
Bakan naa lo ran gbogbo awọn to n jade du ipo leti wi pe ki wọn ma ṣe gbagbe iwe gbigba alaafia laaye ti wọn tọwọ bọ laipẹ yii, to si ni ko tii si nnkan to yi iwe naa pada titi di akoko yii.
 
O fi kun ọrọ rẹ pe ohun to da oun loju ni pe ẹgbẹ oṣelu APC ti padanu ireti wọn pẹlu ohun to wa nilẹ lakoko yii, eyi to sọ pe o n jẹ iṣoro fun wọn lati tete bẹrẹ sii kọ iwe igbejọba silẹ wọn.
 
Siwaju sii lo kọminu lori bi ẹgbẹ APC ṣe lọ ba patako ipolongo oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọnarebu Ọladipupọ Adebutu, iyẹn Lado jẹ, to si ni iwa ti ko bojumu ni wọn n wu kaakiri.
 
Bakan naa lo rọ awọn ọmọ ẹgbẹ PDP lati ma ṣe doju ija kọ ẹnikẹni, ati pe ki wọn jẹ ẹni to n tẹle ofin, to si fi da wọn loju pe igbese ofin ti n lọ labẹlẹ, eyi ti yoo dẹkun gbogbo iwa ibajẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI