Ijọba ipinlẹ Kwara ti se ikilọ fun gbogbo awọn ọga ileewe girama kaakiri ipinlẹ naa lati dẹkun gbigba owo idanwo ti ijọba ko fọwọ si, bi ẹẹ kọ, ijọba sọ pe ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ yoo fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ.
Ninu atẹjade ti kọmiṣanna fọrọ eto ẹkọ, Arabinrin Mary Kẹmi Adeọṣun gbe jade lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Peter Amọgbọnjaye gbe sita lo ti sọ pe lo ti sọ pe ijọba ipinlẹ naa ko faaye silẹ fun gbigba owo idanwo ti ko tọ lọwọ awọn akẹkọọ.
Ijọba Kwara ni ọga ileewe yoowu tọwọ ba tẹ wi pe o gba owo idanwo ti ko tọ lọwọ awọn akẹkọọ rẹ yoo fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ, ati pe iṣẹ ati awọn ẹtọ rẹ lo fi n ṣere.
Wọn ni ko saaye jẹun-jẹun mọ f'awọn ọga ati olukọ ileewe mọ, nipa ilọnilọwọ gba bii gbigba owo ti ko ba ofin mu lọwọ awọn akẹkọọ, eyi ti wọn lo wa ninu ilana lati mu idagbasoke ba eto ẹkọ.
Ṣaaju asiko naa ni Adeọṣun ti bawọn ọga ileewe girama ṣe ipade lati ṣe ikilọ naa fun wọn, to si gba wọn lamọran lati maa gbiyanju nipa titẹle ilana ati ofin eto ẹkọ.
No comments:
Post a Comment