Ọkọ̀ rélùwéè rún ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wómúwómú l'Abuja, obìnrin tó wàá dágbére f'áyé lójú ẹsẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, December 15, 2022

Ọkọ̀ rélùwéè rún ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wómúwómú l'Abuja, obìnrin tó wàá dágbére f'áyé lójú ẹsẹ̀


Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Abuja ti fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé ìjàmbá rélùwéè àti mótò ti gba ẹ̀mí ènìyàn kan ní àdúgbò Kubwa.

Nínú ìkéde kan tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ọ̀hún gbé jáde, alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá náà, DSP Josephine Adeh, sọ pé àwọn dókítà tó wà níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹlẹ̀ sọ pé ìjàmbá náà gba ẹ̀mí ènìyàn kan tó jẹ́ obìnrin.

Ó ní ìwádí ti bẹ̀rẹ̀ lórí ohun tó ṣokùnfà ìjàmbá náà.

Ó fi kún u pé wọn yóò dá àwọn pátákó ìtọ́nisọ́nà padà sí ojú ọ̀nà rélùwéè láti dẹ́kun irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI