Ẹ tun wo oju awọn adigunjale tọwọ tẹ l'Ado Ekiti - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, December 15, 2022

Ẹ tun wo oju awọn adigunjale tọwọ tẹ l'Ado Ekiti


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti foju awọn afurasi adigunjale meje kan han fawọn araalu, ti wọn si ni gbogbo wọn ni yoo foju ba ile-ẹjọ laipẹ, iyẹn lẹyin ti iwadii ba tubọ pari.
 
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Sunday Abutu lo foju gbogbo wọn han fawọn akọroyin niluu Ado-Ekiti.
 
Gẹgẹ bi Abutu ṣe ṣalaye, o ni ile itaja nla kan ti a mọ si Warehouse lawọn mejeeje ọhun lọ digun ja algbegbe Km 4, oju ọna Iworoko niluu Ado-Ekiti.
 
Abutu lawọn ara agbegbe naa ni wọn ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo, ti wọn fi bẹrẹ iṣẹ iwadii wọn, to si ni aṣiri awọn mẹjọ lo tu si wọn lọwọ, ṣugbọn ti ẹnikan yooku wọn raaye salọ.
 
Donne Houndetounkpo, ẹni ọdun marundinlọgbọn; Coker Akeem, Adewọle Ọlatunde, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn; Olowoṣile Bukunmi, ẹni ọdun marundinlọgbọn; Ajilẹyẹ Deborah, ẹni ọgbọn ọdun; Paul Jonati, ẹni ọdun mejilelọgbọn ati Ojo Micheal, toun jẹ ẹni ọdun mọkanlelọgbọn lọwọ palaba wọn segi.
 
Abutu tẹsiwaju pe ninu ifọrọwerọ t'awọn ṣe fun gbogbo wọn, ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe Akinlẹyẹ Ojo lo na papa bora, ti ọwọ ko si tii tẹ

Bẹẹ lo sọ pe ọga awọn, Moronkeji O. Adeṣina ti paṣẹ pe ki wọn lọ foju wọn ba ile-ẹjọ lati gba idajọ to ba tọ si wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI