Qatar 2023: Eyi lawọn to gba bọọlu sawọn julọ ninu idije ife ẹyẹ agbaye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, December 15, 2022

Qatar 2023: Eyi lawọn to gba bọọlu sawọn julọ ninu idije ife ẹyẹ agbaye


Lẹyin ifẹsẹwọnsẹ to kangun si aṣekagba, iyẹn Semi-Final, eyi to waye laaarin ikọ ẹgbẹ agbabọọlu France ati Morocco l'Ọjọru, Wẹsidee to kọja yii, a ti mu awọn to gba bọọlu sawọn julọ ninu awọn agbabọọlu to kọpa nibi idije ife ẹyẹ agbaye to n lọ lọwọ lorileede Qatar.
 
Bẹ o ba gbagbe, aami ayo meji si oodo ni ikọ ẹgbẹ agbabọọlu lati orileede France fi lu awọn alatako wọn lati orileede Morocco, ti wọn fi peregede lọ si aṣekagba.
 
Aami ayo mẹta si oodo ni ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Argentina fi lu Croatia lọjọ Iṣẹgun, Tusidee.
 
Lionel Messi lo pada ba Kylian Mbappe pẹlu goolu marun-un-marun-un.
 
Goolu marun-un: Lionel Messi ati Kylian Mbappe 
 
Goolu mẹrin: Olivier Giroud ati Julián Álvarez.
 
Goolu mẹta: Marcus Rashford, Bukayo Saka, Cody Gakpo, Alvaro Morata, Richarlison, Gonçalo Ramos ati Enner Valencia.
 
Goolu meji: Mohammed Kudus, Ritsu Doan, Mehdi Taremi, Vincent Aboubakar, Giorgian de Arrascaeta, Robert Lewandowski, Neymar, Ferran Torres, Rafael Leão, Kai Havertz, Harry Kane, Niclas Fullkrug, Bruno Fernandes, ati Wout Weghorst.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI