Real Estate: Ileeṣẹ Pelican gbe eto idanilẹkọọ kalẹ lori ọna lati gbaradi fun ile kikọ ta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 28, 2022

Real Estate: Ileeṣẹ Pelican gbe eto idanilẹkọọ kalẹ lori ọna lati gbaradi fun ile kikọ ta

 
 
Lojuna lati mu irọrun de f'awọn to fẹẹ wọnu iṣẹ ilẹ ati ile kikọ ta, gbajugbaja ileeṣẹ to n ṣowo ilẹ ati ile kikọ n'ipinlẹ Ogun, Pelican Valley Estate ti gbe eto idanilẹkọọ kalẹ
 
Eto idanilẹkọọ naa lo da lori bi a ṣe n gbaradi fun owo nina nipa okoowo ile kikọ, eyi ti oloyinbo n pe ni 'Easy Budgeting For Real Estate'.

Alaṣẹ ati oludisilẹ Pelican Valley Estates, Ọmọwe Babatunde Adeyẹmọ to gbe eto idanilẹkọọ ọfẹ naa kalẹ f'awọn eeyan lo sọ pe lara awọn ohun ti ileeṣẹ naa da lori ni lati maa gbe idanilẹkọọ kalẹ f'awọn eeyan.
 
O ni idanilẹkọọ naa yoo fun awọn to ti wa ninu okoowo ilẹ tita ati ile kikọ ta, pẹlu awọn to ṣẹṣẹ fẹẹ darapọ ati awọn to n gbero lati wọnu okoowo naa ni anfaani lati mọ iye owo ti wọn gbọdọ maa na ki wọn too bẹrẹ.
 
Nibi akanṣe eto idanilẹkọọ naa ti wọn pe akori rẹ ni "Real Estate Advisory Freestyle" la gbọ pe awọn oludasilẹ ileeṣẹ to n ri sọrọ ilẹ ati dukia tita ti sọrọ nipa awọn ohun to le mu idagbasoke ba iṣẹ naa.
 
Nibẹ ni wọn ti lo awọn fọnran perete ti wọn ti ṣeto silẹ fun idanilẹkọọ naa.

Ọmọwe Adeyẹmọ gba gbogbo awọn to kopa nibi eto idanilẹkọọ naa lamọran lati maa ṣe agbeyẹwo ohun ti wọn ba fẹẹ ṣe daadaa, ki wọn ma ba a padanu tabi jẹ gbese lọjọ iwaju.

O ni ohun to ṣe pataki ni lati ni dukia, iyẹn ilẹ ti wọn ba fẹẹ fi ṣowo, ki wọn si rii daju pe wọn ṣe gbogbo ẹtọ to ba yẹ, ki wọn si gba awọn iwe to ba yẹ lori ilẹ wọn ko to di pe wọn tẹsiwaju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI