Omiyale: Ọkan wa balẹ wi pe Tinubu maa ṣe atunṣe si afara Niger - AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 28, 2022

Omiyale: Ọkan wa balẹ wi pe Tinubu maa ṣe atunṣe si afara Niger - AbdulRazaq


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti sọ pe ọkan oun balẹ wi pe iṣakoso ẹgbẹ oṣelu APC labẹ Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu yoo wa atunṣe si afara Niger to n fa iṣoro omiyale, agbara ya ṣọọbu.
 
O ni ki awọn araalu riii daju pe wọn dibo fun Tinubu ninu eto idibo to n bọ lọna yii, nitori pe ẹnikan ṣoṣo to le yi itan orileede Naijiria pada si rere niyẹn.
 
AbdulRazaq lo sọrọ naa niluu Lafiagi, nibi ti wọn ti we lawaani fun un gẹgẹ bii Sadaukin tiluu Lafiagi labẹ Ẹmir ilu Lafiagi, Alaaji Muhammed Kudu Kawu. 
 
O ni ṣiṣe Tinubu yoo ṣe afara Niger, yoo mu opin de ba omiyale to n ṣẹlẹ lọdọọdun, eyi to n fi ẹmi ati dukia awọn araalu ṣofo danu, ti gbogbo ajalu ọdọọdun naa yoo si d'ohun igbagbe patapata.

AbdulRazaq ni anfaani nla ni yoo jẹ fun gbogbo awọn ara ẹkun Ariwa ati agbegbe orileede Naijiria bi Tinubu ba wọle gẹgẹ bi Aarẹ Naijiria.

Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe ọkan pataki lara awọn akanṣe iṣẹ ti ijọba Kwara yoo mu lokunkundun fun ijọba Tinubu ni afara Niger naa, iyẹn ni kete ti Tinubu ba de ori aleefa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI