Wọn fi gbajugbaja agba akọroyin j'oye Baaroyin l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 28, 2022

Wọn fi gbajugbaja agba akọroyin j'oye Baaroyin l'Abẹokuta


Gbogbo ilu Abẹokuta n'ipinlẹ Ogun lo di gaga lonii, Ọjọru, Wẹsidee nigba ti wọn fi gbajugbaja agba akọroyin nipinlẹ naa, Johnson Onifade jẹ oye Baaroyin ilu Oke-Ṣajẹ.

Baalẹ ilu Oke-Ṣajẹ, Oloye Tajudeen Adesanya lo jawe oye le Onifade lori, to si tun fun un ni ọpa aṣẹ, to fi mọ iwe ẹri.

Odu ni Johnson Onifade, akọroyin fun ileeṣẹ National Waves, kii ṣaimọ f'oloko lagboole akọroyin, to si tun jẹ ọkan lara awọn olootu fun iwe iroyin First Weekly Magazine.

Nigba to n sọrọ, Oloye Adesanya to jẹ Baalẹ Oke-Ṣajẹ niluu Ẹgba, o ni eeyan pataki ni Oloye Onifade jẹ niluu Ẹgba, paapaa n'ipinlẹ Ogun, to si ti ko ipa rere ninu idagbasoke ipinlẹ naa, nipa gbigbe awọn otitọ iroyin jade.

Oloye Adesanya ni latigba ti Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba ti wa lori ipo gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ogun loun ti mọ Onifade, to si loun ko ba iwa buruku lọwọ.

Siwaju sii lo ni ọkan pataki lara awọn akọroyin to n jẹ ki iṣẹ iroyin kikọ maa wu awọn eeyan lati ṣe ni Onifade jẹ, to si ti ba oniruuru ijọba ṣiṣẹ nipinlẹ Ogun ati kaakiri orileede Naijiria.

Bakan naa lo sọ pe ipa ti Oloye tuntun naa ti ko ninu eto idagbasoke ilu Oke-Ṣajẹ ko ṣee fọwọ rọ sẹyin, idi pataki to fi lo yẹ k'awọn fi ẹbun oye naa da a lọla.

Nigba toun naa dupẹ lọwọ Baalẹ Oke-Ṣajẹ, Oloye Adesanya, oloye tuntun naa sọ pe idunnu nla lo jẹ f'oun nigba ti wọn fi lẹta ranṣẹ s'oun lati wa a di Baaroyin ilu naa.

Onifade sọ pe kii ṣe oye toun ti la ala rẹ ri tẹlẹ, tabi wi pe boya oun fi owo ra a, o ni lara iwa rere toun ti ṣe silẹ, paapaa laaarin ilu naa, lo mu ki wọn ronu ohun rere kan oun.

Nibẹ lo ti fi da gbogbo ilu Oke-Ṣajẹ loju wi pe oun yoo tubọ rii daju pe gbogbo awọn ojuṣe oun gẹgẹ bii Baaroyin loun yoo maa ṣe lati rii pe ilu naa n ni itẹsiwaju, paapaa lẹka eto ọrọ aje.
 
Gbogbo awọn oloye ilu Oke-Ṣajẹ, to fi mọ awọn ọmọ ilu ni wọn l'awọon fọwọ si Oloye Johnson Onifade gẹgẹ bii Baaroyin ilu naa, nitori pe ẹni kan ṣoṣo to tọ lati j'oye naa niyẹn.

Diẹ lara awọn fọto bi eto naa ṣe lọ:
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI