Aye o! Wọn ba oku ọkunrin mẹta ti wọn yọ ẹya ara wọn lọ n'Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 28, 2022

Aye o! Wọn ba oku ọkunrin mẹta ti wọn yọ ẹya ara wọn lọ n'Ibadan


Ariwo ati igbe ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu awọn eeyan to wa n'ijọba ibilẹ Akinyẹle, ilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ l'ọjọ Aje, Mọnde to kọja yii nigba ti wọn ba ọkunrin mẹta kan lẹgbẹ opopona.
 
Kii ṣe bi wọn ṣe ba oku awọn mẹta naa lo n jẹ kayeefi, bi ko ṣe pe wọn tun yọ ẹya ara wọn lọ, pẹlu erongba wi pe ṣe ni wọn fi wọn ṣẹṣo.
 
Ibuodoko Office, iyẹn Office Bus Stop to wa nikọja ile-epo World Oil to wa loju ọna Ibadan siluu Ọyọ ni wọn ti ba okun awọn ọkunrin mẹta naa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
AWIKONKO gbọ pe ọkan lara awọn oku naa ni wọn ge ori rẹ lọ, ti wọn si yọ ẹya ara awọn meji yooku lọ.
 
Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ko tii le f'idi awọn to ṣiṣẹ buruku naa mulẹ, ti wọn si lawọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI