2023: Ijọba ipinlẹ Ogun kede isinmi ọjọ meji f'awọn oṣiṣẹ lati gba kaadi idibo alalopẹ wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 22, 2023

2023: Ijọba ipinlẹ Ogun kede isinmi ọjọ meji f'awọn oṣiṣẹ lati gba kaadi idibo alalopẹ wọn


Ijọba ipinlẹ Ogun labẹ iṣakoso Gomina Dapọ Abiọdun ti kede isinmi ọlọjọ meji fun gbogbo awọn oṣiṣẹ jakejado ipinlẹ naa lati lọ gba kaadi idibo alalopẹ wọn, ki wọn ba a le kopa ninu eto idibo apapọ to n bọ lọna l'oṣe keji, ọdun 2023 ti a wa yii.
 
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinlelogun ati Ọjọru, Wẹsidee, ọjọ karundinlọgbọn ni ijọba kede peki gbogbo awọn oṣiṣẹ lo anfaani rẹ lati lọ gba kaadi idibo alalopẹ wọn, ki asiko naa too lọ.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Ọgbẹni Kunle Ṣọmọrin fi sita lonii, ọjọ Aiku, Sannde, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lo ti sọ pe lati le jẹ ki awọn oṣiṣẹ naa ṣe ojuṣe wọn gẹgẹ bi ọmọ ilu ni.

O ni ipinnu naa yoo fun awọn oṣiṣẹ lanfaani lati gba kaadi idibo alalopẹ wọn pẹlu bi ajọ eleto idibo lorileede yii ṣe fi kun gbedeke ọjọ ti eto gbigba kaadi idibo naa yoo kasẹ nilẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2023.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI