Ẹ ma jẹ ki APC fi akanṣe iṣẹ pajawiri tan yin jẹ o - Aderinokun, oludije s'ipo aṣofin ni PDP pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 22, 2023

Ẹ ma jẹ ki APC fi akanṣe iṣẹ pajawiri tan yin jẹ o - Aderinokun, oludije s'ipo aṣofin ni PDP pariwo sita


Oludije s'ipo aṣofin ipinlẹ Ogun lẹkun aarin gbungbun ipinlẹ naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Olumide Aderinokun ti parọwa sawọn araalu lati ma ṣe jẹ ki ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC fi akanṣe iṣẹ pajawiri, opin saa tan wọn jẹ.
 
Aderinokun sọ pe ẹgbẹ oṣelu APC ko ni nnkan rere ti wọn fẹẹ ṣe f'awọn araalu mọ, ṣugbọn to ni wọn tun n wa gbogbo ọna lati pada s'ipo naa, ki wọn le maa fiya jẹ araalu siwaju sii.
 
O ni ki onikaluku dibo fun ẹni to ba wuu, iyẹn awọn adari ti wọn fọkan tan, paapaa ẹgbẹ oṣelu PDP, nitori pe awọn nikan ni ọna abayọ si iṣoro Naijiria lasiko yii.
 
Aderinokun lo sọrọ naa laipẹ yii lakoko to ṣabẹwo si agbegbe Ọlambẹ, ijọba ibilẹ Ifọ nipinlẹ naa. Nibẹ lo ti bawọn ọmọ ẹgbẹ 'Ṣaa Ṣaa Ṣaa' tii ṣe Olambe Community Development Council ati Aarẹ Boluwatifẹ Community Development Council (CDC) sọrọ lori eto idibo to n bọ lọna.
 
Bakan naa lo jẹ ki wọn mọ awọn ipinnu rere to ni fun wọn nigba to ba de ori ipo aṣofin to n foju sọna fun.
 
Akinruyiwa tiluu Owu, Abẹokuta naa tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe ipo ti opopona Ifọ wa ko ṣee fẹnu sọ, nitori pe ijọba ko ri t'awọn araalu naa ro, bẹẹ lo ṣeleri wi pe yoo di ṣiṣe ni kete toun ba de ori ipo, nitori pe oun mọ ọna toun yoo fi ba awọn tọrọ naa kan sọrọ, ti iṣẹ ọhun yoo fi ya.

"Ohun to foju han gbangba ni pe ijọba APC ti kuna patapata. Gbogbo opopona to wa nijọba ibilẹ Ifọ lo ti bajẹ kọja afẹnusọ. Eruku oju ọna wa ko jẹ ka gbadun, ẹ ma jẹ ki wọn fi awọn akanṣe iṣẹ opin saa wọn tan yin jẹ.

"Mo fi n da yin loju pe PDP yoo jẹ ki n nnkan ṣiṣẹ papọ si rere fun igbadun gbogbo awọn ara ijọba ibilẹ yii, paapaa pẹlu ileri ti oludije s'ipo gomina labẹ asia PDP, Ọnarebu Ọladipupọ Adebutu tun ṣe nipa dida agbara pada f'awọn ijọba ibilẹ, ati eto ironilagbara ti emi naa ni lọkan lati ṣe.
 
"Ati ọmọde ati agba ni ọrọ ẹgbẹ oṣelu APC ti su patapata, a si gbọdọ ṣetan lati tun ipinnu wa ṣe nipa lile wọn danu lakoko eto idibo to n bọ yii."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI