AbdulRazaq bu ọwọ lu eto iṣuna ọdun 2023, o n'iṣẹ idagbasoke ṣi n tẹsiwaju - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, January 25, 2023

AbdulRazaq bu ọwọ lu eto iṣuna ọdun 2023, o n'iṣẹ idagbasoke ṣi n tẹsiwaju


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti bu ọwọ lu iwe abadofin ti eto iṣuna ọdun 2023 ti a wa yii, eyi to gbe lọ siwaju ile igbimọ aṣofin, ipinlẹ Kwara lọdun 2022.
 
Bẹ o ba gbagbe, ọgbọn ọjọ, oṣu kọkanla, ọdun 2022 ni Gomina AbdulRazaq gbe aba eto iṣuna ọdun 2023 ti a wa yii lọ siwaju ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa lati ṣe agbeyẹwo rẹ, lẹyin eyi ni awọn aṣofin bu ọwọ lu.

Eto iṣuna naa ni wọn lo din diẹ ni igba biliọnu (N188,845,603,561.00) naira, eyi to din diẹ ni N189,436,248,054.00 ti gomina ti kọkọ gbe lọ lọgbọn ọjọ, oṣu kọkanla naa.
 
Gomina AbdulRazaq sọ pe wọn yoo tun fi tẹsiwaju ninu awọn akanṣe iṣẹ to ti n lọ lọwọ tẹlẹ, bẹẹ lawọn akanṣe iṣẹ miran yoo tẹsiwaju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI