Bi AbdulRazaq ṣe n yan awọn ọdọ s'ipo oṣelu, o odaju pe ọjọ iwaju Naijiria dara - Ọbasanjọ gbe oṣuba kare fun gomina Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, January 25, 2023

Bi AbdulRazaq ṣe n yan awọn ọdọ s'ipo oṣelu, o odaju pe ọjọ iwaju Naijiria dara - Ọbasanjọ gbe oṣuba kare fun gomina Kwara


Aarẹ tẹlẹri lorileede Naijiria, Oloye Oloṣẹgun Ọbasanjọ ti sọ pe pẹlu igbesẹ ti gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq n gbe nipa fifi awọn ọdọ s'ipo oṣelu, o ti n daju pe ọjọ iwaju orileede Naijiria yii yoo dara.
 
O ni ohun to dara ni ki awọn oloṣelu asiko yii maa fun awọn ọdọ laaye ninu ipo oṣelu, eyi ti yoo jẹ ki ọkan awọn agbaagba balẹ wi pe wọn maa mu orileede yii de ilẹ ileri lai nibẹru.
 
Aarẹ tẹlẹri naa lo sọrọ yii lakoko to ṣabẹwo si Gomina AbdulRazaq niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara.

Ọbasanjọ la gbọ pe o lọ siluu Ilọrin lati bawọn ṣayẹyẹ igbeyawo laaarin awọn ọmọ gbajugbaja olokoowo nni, Alaaji Kamarudeen Yusuf (KAMWIRE) ati Alaaji Adelọdun Ọba Adebayọ.
 
Nibẹ lo ti sọ pe oriṣiriṣi ẹri loun ti gbọ nipa ọna ti gomina Kwara n gbe iṣakoso rẹ gba, to si lo jẹ ohun iwuri f'oun, eyi to f'ọkan oun balẹ pe ọjọ Iwaju ipinlẹ naa dara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI