Ohun to ṣẹlẹ ni ipinlẹ Ogun lẹnu ọjọ mẹta yii ni ko tii sẹni to le sọ, paapaa lori bi awọn eeyan ṣe n dawati lojiji, ti ko si tii sẹni to le sọ pato ibi ti awọn eeyan naa n wa.
Awọn ti ẹ n woju wọn yii ni iya ati ọmọ ti a gbọ pe awọn ajinigbe tun jigbe l'Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Obinrin naa, Abọsẹde Adeboye ati ọmọ rẹ, Ibrahim Adeboye la gbọ pe awọn agbebọn lọ ka mọ inu ṣọọbu to ti n ta ọja niluu Ipẹru-Rẹmọ, ipinlẹ Ogun.
A gbọ pe bi wọn ṣe lọ ka mọ ṣọọbu, lo ti sare lọ tọrọ owo lọwọ awọn ti wọn jọ wa nitosi, ṣugbọn ti ko pada ri iye ti wọn n beere lọwọ ẹ gba, eyi lo jẹ ki wọn gbe e lọ.
Imobido quarters, Ipẹru Rẹmọ, ipinlẹ Ogun ni iṣẹlẹ naa ti waye ni nnkan bi aago mẹwaa aarọ, ọjọ kẹwaa, oṣu yii.
Ki ẹnikẹni to ba mọ ibi ti wọn le wa obinrin naa ati ọmọ rẹ si fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti, tabi ki wọn pe nọmba Arabinrin Lukmọn Tanwa yii 08104471823.
No comments:
Post a Comment