Awọn ọlọja dide ipolongo idibo saa keji fun AbdulRazaq ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, January 11, 2023

Awọn ọlọja dide ipolongo idibo saa keji fun AbdulRazaq ni Kwara


Orin 'AbdulRazaq, maa ba iṣẹ rẹ lọ, iṣẹ maa n tẹ wa lọrun' ni gbogbo awọn ọlọja patapata kaakiri igboro ilu Ilọrin, ipinlẹ Kwara nkọ fun gomina wọn, AbdulRahman AbdulRazaq lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee.

Wọn l'awọn ti ṣetan lati polongo idibo gomina fun ẹni to n mu ilọsiwaju ati idagbasoke ba ipinlẹ naa.

Awọn ọlọja naa ti wọn wa ni Ọja Ọba niluu

Nigba to n gba ẹnu awọn ọlọja naa sọrọ, Iyalọja Ọja Ọba, Alaaja Mariam Ẹlẹfun to ṣagbekalẹ eto ipolongo idibo naa sọ pe ẹni to n ṣe ifẹ araalu ni gomina wọn.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI