Abiọdun ja ilẹkun ṣọọṣi, lo ba ji gbogbo foonu to wa nibẹ gbe n'Ilaro - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, January 28, 2023

Abiọdun ja ilẹkun ṣọọṣi, lo ba ji gbogbo foonu to wa nibẹ gbe n'Ilaro


Ọrọ buruku toun tẹrin lọrọ gendekunrin, ẹni ọdun mọkandinlogun kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Abiọdun Elegbede, ẹni ti wọn lo ja ilẹkun ṣọọṣi, to si lọ ji gbogbo foonu to wa nibẹ gbe salọ.
 
Yatọ si ṣọọṣi ti Abiọdun ja ilẹkun rẹ, wọn lo tun fọ ile meji ọtọọtọ lagbegbe Agọ Ararọmi to wa ni Ilaro, ijọba ibilẹ Yewa, ipinlẹ Ogun, nibi to tun ti ji foonu gbe.
 
Awọn ara agbegbe naa ti wọn kofiri Abiọdun ni wọn ranṣẹ pajawiri sawọn oṣiṣẹ eleto aabo So-Safe Corps nipinlẹ naa fun iranwọ, ti awọn yẹn naa ko si fi falẹ rara.
 
Mọruf Yusuf to jẹ agbẹnusọ So-Safe nigba to n ṣalaye bo ṣe ṣẹlẹ f'AWIKONKO, o ni nnkan bi aago mejila si meji oru Ọjọbọ tii ṣe Tọside, ọsẹ yii ni Abiọdun ṣiṣẹ buruku naa, ko to di pe wọn ranṣẹ pe awọn laago meji oru ọjọ naa.
 
Agbegbe Ajegunlẹ to wa niluu Ipobẹ, ijọba ibilẹ Ipokia ni wọn sọ pe Abiọdun n gbe, nibẹ lo si ti wa jale n'Ilaro.
 
Yusuf sọ pe foonu Itel mẹrin ọtọọtọ ni wọn ri gba lọwọ Abiọdun ni kete tọwọ palaba rẹ segi, to si ni ọga awọn, Sọji Ganzallo ti paṣẹ pe ki wọn lọ faa le awọn ọlọpaa ẹkun Ilaro lọwọ lati ṣewadi ẹ siwaju sii, ki wọn le foju rẹ ba ile ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI