Iwa ibajẹ ni lati maa sọrọ abuku s'awọn adari Naijiria lori ikanni ayelujara - Alaṣẹ ileeṣẹ Pelican gba awọn ọdọ lamọran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, January 28, 2023

Iwa ibajẹ ni lati maa sọrọ abuku s'awọn adari Naijiria lori ikanni ayelujara - Alaṣẹ ileeṣẹ Pelican gba awọn ọdọ lamọran


Alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ to n ta ile, ilẹ ati dukia igbalode kaakiri orileede Naijiria, iyẹn Pelican Valley Nigeria Limited, Ọmọwe Babatunde Adeyẹmọ ti sọ pe iwa ibajẹ gbaa ni k'awọn ọdọ orileede yii maa sọrọ abuku s'awọn adari wọn lori ikanni ayelujara kaakiri.

O ni kii ṣe ohun to ba oju mu rara fun idagbasoke orileede, to si ni kaka ki wọn maa sọrọ abuku s'awọn adari, ki wọn lo akoko wọn lati wa ọna abayọ si ohun to le tan iṣoro ara wọn.

Gbajugbaja olokoowo dukia naa lo sọrọ yii niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun l'Ọjọbọ tii ṣe Tọside, ọsẹ yii niluu Abẹokuta lakoko to n gba awọọdu ileeṣẹ to n ta dukia to dara julọ nipinlẹ Ogun f'ọdun 2022, eyi ti ileeṣẹ iroyin Gateway News Update gbe kalẹ.

O ni pupọ awọn oloṣelu lo wa nita lakoko yii ti wọn n jade fun ipo oṣelu kan abi omiran, eyi to ni k'awọn ọdọ farabalẹ lati gbọ oniruuru anfaani ti ẹnikọọkan wọon fẹẹ mu wa fun idagbasoke, ki wọn si muu lo fun ara wọn.
 
Adeyẹmọ, ẹni to ti f'igba kan ri jẹ ilu mọ-ọn ka akọroyin naa tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe ohun to dara julọ ni k'awọn ọdọ maa wa gbogbo ọna anfaani ti yoo jẹ ki wọn le ronu nnkan ti wọn le ṣe lati maa fi ri owo, ti erongba wọn ni rere yoo si wa si imuṣẹ.
 
Eto ayẹyẹ idasilẹ ọdun kẹtadinlogun ti ileeṣẹ Gateway News Update lo waye ninu gbọngan ayẹyẹ Valley View to wa nile ijọba ipinlẹ Ogun, eyi to f'ikalẹ sagbegbe Oke-Igbein niluu Abẹokuta, nibi ti wọn ti faami ẹyẹ da awọn to ṣe daadaa julọ l'ọdun 2022 n'ipinlẹ Ogun.
 
Bakan naa lo sọ pe k'awọn ọdọ tete maa ronu anfaani papakọ ofurufu akẹru ti ọkan lara awọn oludije s'ipo gomina n kọ lọwọ, lati mọ iru okoowo ti wọn yoo ṣe, eyi ti yoo jẹ ki papakọ ofurufu naa wulo fun wọn lọjọ iwaju.
 
Nibi ti wọn ti n gba awọọdu naa
 
Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe awọn naa ti bẹrẹ iṣẹ eto agbẹ ati ọgbin igbalode, eyi ti papakọ ofurufu naa yoo fi wulo fun wọn nigba ti iṣẹ ba bẹrẹ nibẹ lẹkunrẹrẹ, eyi to l'awọn yoo maa ko gbogbo ire oko wọn lọ ta lawọn ọja igbalode to wa lagbaaye.
 
O tun fi kun ọrọ rẹ pẹlu idaniloju wi pe ohun to ṣee ṣe ni ki ọdọ ṣiṣẹ ti yoo ni laari lorileede Naijiria lai lu jibiti, tabi huwa ọdaran tabi ki wọn salọ si ilẹ okeere, eyi ti awọn eeyan tun n pe ni JAPA lasiko yii.

Lara awọn to tun gba aami ẹyẹ lọjọ naa ni Gomina Dapọ Abiọdun; Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Gbadebọ; Giwa ile ẹkọ fasiti Chrisland, Ọjọgbọn Chinedum Peace Babalọla; ọga ọlọpa ẹkun Kemta, CSP Adeniyi Adewale; ọga ọlọpaa ẹkun Ọdẹda, CSP Felix Ọlajogun; Kọmiṣanna feto iroyin nipinlẹ Ogun, Waheed Oduṣile ati awọn miran.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI